Ko si nkan to le so pe ki n ma dije dupo gomina lodun 2019 - GNI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 3, 2017

Ko si nkan to le so pe ki n ma dije dupo gomina lodun 2019 - GNI


Gbajumo oloselu nni, to tun je okan lara awon oludije sipo gomina ipinle Ogun labe egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP, Omoba Gboyega Nasiru Isiaka ti so pe ko si nkan to le di oun lowo lati ma se jade dije du ipo gomina nipinle Ogun nitori pe ife awon araalu je oun logun pupo.

GNI
Omoba Isiaka soro yi lose to koja nibi apejo ti won ti yan awon oloye egbe e kan to da sile fun ti ipolongo idibo, iyen The Believe Movement ni aarin gbungbu ipinle naa.

Fun eni to ba mo bosenlo lori awuyewuye kan to n lo pe won ti pin bi ipo naa yoo se lo, ti eon so pe Senato Adeola Yayi ni won fee lo lati koju eni ti Gomina Amosun fee fa kale fun ipo naa lodun 2019.

GNI so pe oun yoo dupo gomina gomina lodun 2019, oun yoo si wole nitori pe o da oun loju gege bi igbagbo toun ni.

O tesiwaju pe kawon to n so isokuso lo panumo pe oun ti lo ledi apo po pelu awon kan nipa pe oun ko nii jade dupo naa lodun 2019. O so pe ipo naa da oun loju nitori pe oun kun oju osuwon lati di gomina.

Bakanna lo tun so pe ipinu to mu oun jade dupo naa lodun 2011 ati 2015 ko tii yi pada.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI