Aala awon onisango |
Gege bi AWIKONKO
se gbo, lojo kerin osu yi ni nnkan bi aago mokanla asale ni won so pe ojo kan ro,
to si san ara, ara yi ni won lo o wole to Fausat atoko e, tawon eeyan mo si
Oluso lori beedi ti won jo sun si, to si seku pa a.
Bo tile je
pe se ni won so pe aditu loro ara naa je fawon bo se je pe eemeeta otooto ni
won ni ara naa san wonu ile naa, to si ba nnkan je, yato si wipe o seku pa
Fausat.
Bawon kan
se n so pe oro naa lowo ninu nitori pe ara kii deede san paayan, bee lawon kan
n ni ise buruku to wa lowo oko arabinrin naa, iyen Ogbeni Olorunwa ti won ni
Oluso ni lo dahun lori iyawo e, to si so awon ebi e sinu ekun ati laala ti won
n ba kiri lowo bayii.
AWIKONKO
gbo pe ko tii ju odun marun ti obinrin naa ko de odo okunrin naa ni isele
buruku yi waye. Bakanna la tun gbo pe okunrin naa kii baayan se ladugbo, paapaa
nilu Gbayunre lati nnkan bi odun marundinlogoji ti won lo o ti wa pelu won.
Ogbeni Oatinwo, Alaga CDA |
Alaga
idagbasoke agbegbe Irewolede toro naa ti sele, Ogbeni Olatinwo Saka Adesina,
nigba to n IROYIN OWURO soro lojobo Tosde ose to koja lori isele naa so pe
aditu loro ara naa si n je fawon nitori pe awon ko tii ni ifokanbale lori e
latigba toro naa ti sele.
Okunrin
naa so pe inu isooru ni soosi loun wa lale ojo naa, nigba tawon gbo bi ara naa
se san, ohun ti ara naa gbe yato sawon ara to maa n san nigba tojo baa n ro,
maiki gan an jabo lowo oga akorin, koda, awon eeyan inu soosi gan fee takiti
lojo naa.
O ni ko
tii ju bi ogun iseju lo toun ti ri awon agbaagba ladugbo ti won wa ba oun pe
ara to san naa ti pa iyawo Oluso, sugbon awon ko tii le wole ayafi ti ile ba
tubo mo si.
O tesiwaju
pe laaro kutu ojo keji, iyen ojo Wesde lawon ri awon kan ti won wa so pe eran
awon sonu, ohun lawon n wa. O ni oro naa ko tete ye awon iru eran ti won n so,
sugbon nigba to ya, won je ko ye wa pe ara to san naa ti paayan.
Ogbeni
Olatinwo so pe lojobo Tosde lawon bere igbese ni pereu nigba tawon rii pe kii
se kekere loro naa nitori oju tawon fi wo. O ni esekese lawon ti bere igbese
lati setutu lori ki isele naa ma baa tan kaakiri ilu.
Olori Ebi |
Ninu oro
ti olori ebi ilu Gbayunre, iyen Oloye Dada, o so pe bo tile je ara kii deede
san paayan laini idi kan ni pato sugbon oju Olorun lo to gbogbo e, o ni ohun
ogbologbo iwa buruku lo wa lowo Oluso naa nitori pe iran kefa loun je leyin ti
won ti da ilu Gbayunre sile.
O ni iru
nnkan bayii ko sele ri latigba ti ilu naa ti wa, iyalenu loro naa si n je
fawon, nitori pe sadede lawon gbo pe sango mu enikan ni soosi Oluso, nibe ni
aya oun ti ja pe afigba ti okunrin yi ko wahala wo inu ilu wa ba awon.
O tesiwaju
pe o ti le ni ogbon odun tawon ti jo n gbe ilu ti ko sib a enikeni se papo. O
ni awon ti gbe igbese lati fejo e sun awon olopaa paapaa ijoba ipinle Ogun lati
wa wa nnkan se si oro e.
Suraju to
je okan lara awon omo oloogbe naa nigba to n soro pelu omije loju so pe ni
nnkan bi aago kan oru ni won pe awon pe ara san pa iya awon lori beedi, sugbon ibi
tawon wa ko le je kawon foru rin, sugbon nigba tawon de laaro ojo keji tawon de
ile naa, lawon sese ri nnkan to sele.
O ni bawon
se wole tawon ri iya awon nibi to sun si lawon eeyan ti n pariwo pe kawon ma
fowo kan nitori pe se ni ara naa gbo jalajala to si je ori e nikan lawon fi daa
mo pe iya awon ni.
Suraju so
pe oun ko le so pe nnkan bayii pato lo gbe iya awon de odo Oluso naa nitori pe
o ti le ni odun meje ti iya awon ti kuro lodo baba awon ni Idiroko, ti ko si si
omo Kankan lodo won lasiko naa.
O ni ko
tii ju bi odun marun lo tawon gbo pe odo Oluso naa ni iya awon wa bayii, tawon
si wa sibe lati mo ibi ti iya awon n gbe. o ni ohun tohun yoo tun gbo nipe ara
san pa iya awon.
Ohun ti AWIKONKO
tun ri gbo nipe opo igba ni won ti mu Oluso yi lo si tesan olopaa lori pe o ji
eran, adie, isu, bulooku gbe, eyi ti won lo fi n ko soosi e naa. Bee la tun gbo
pe okunrin naa kii ba eeyan se ladugbo.
Sugbon fun
bii wakati mefa ti asojukoroyin AWIKONKO fi wa nilu Gbayunre lati ri okunrin ti
isele naa sele nile e ni a ko fi ri, oun ti a gbo nipe lesekese ti okunrin naa
gbo pe oniroyin ti wa nitosi lo tin a papa bora.
No comments:
Post a Comment