Kasumu gbe majele je nitori esi idanwo JAMBU e ti ko dara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 23, 2017

Kasumu gbe majele je nitori esi idanwo JAMBU e ti ko dara

Kani kii se pe won tete du emi odomokunrin kan ti won pe oruko e ni Kasumu Yusuf Tunde, eni odun mokandinlogun to n gbe lagbegbe Lipede ni Onikoko, Abeokuta ti won lo gbe majele je ni ana ojo Aje Monde, ojo kejilelogun ni, nnkan ti a n ko yi ko ni aa ba maa ko.
 
Gege bi AWIKONKO se gbo, odo iya agba e ni won so pe Yusuf n gbe, nibe lo si ti kawe jade ni ile eko girama Ijemo Titun lodun 2016. Lose to koja yi ni won so pe Yusuf se idanwo JAMB e nilu Abeokuta, to si n retie si lati jade.

Opo awon akeko ti won se idanwo JAMB yi lo je pe idunnu subu lu ayo won nigba ti won lo n woe si idanwo won, nitori pe eni ti won ni maaki e keke ju lo ni igba maaki.

Sugbon oro ko ri be nigba ti ajo JAMB maa gbe esi idanwo Yusuf jade, lo je pe 142 lo gba, to si je ki inu e baje nigba to rii. AWIKONKO gbo pe nigba Yusuf maa fi esi idanwo e han iya to bii lomo, oro-orun ni won lobinrin naa so si Yusuf, eyi to si bii ninu.

Iya Yusuf ti a gbo pe agbegbe Iporo Ake nilu Abeokuta lo ti n ta oti, lo so pe erepa ti po ju omo e Yusuf lo, atipe tete to n ta ko je ko ri aaye kawe fun idanwo JAMB naa. Bee lo tun so pe ako ti po ju omo oun lo, orekore lo n ba rin.

Gbogbo oro buruku ti won so pe iya Yusuf so si lo woo ni akiyemi ara, ti ko si mo nnkan to le se mo nitori itiju, paapaa nitagbangba ti won lobinrin naa ti soro sii.

Bi Yusuf se dele ni nnkan bi aago meta osan ana Monde, lo ba lo gbe ose ti won so pe awon akeko Mapoly ta fun iya agba e, to si gbe e mu. Won ni ki Yusuf to mu ose naa lo ti koko gba ohun ara e sile ninu foonu e, nibi to ti so pe ki won ma sunkun toun ba ku nitori pe ile aye ti su oun.

Won lo so sinu fonran naa pe oro ti iya oun so soun lo tun je koun mu ose naa nitori pe won doju ti oun laarin awon ore oun paapaa awon araadugbo toun ko si le muu mora.

Ohun ti AWIKONKO tun gbo pe yato pe Yusuf gba ohun ara e sile, o tun ko iwe ikeyin sile fawon eeyan lati ka, debi pe to ba ku, won le mo idi iku to ba oun. Won ni se se eyi tan lo ba gbe ose naa mu, to si bo sita.

Ko to iseju meta ti won so pe o mu ose naa, ni ise bere, to si bere sii lo inu mole niwaju ita lai mo pe o ti gbe nnkan mu. Kawon eeyan to sakiyesi pe o n lo inu mole too de odo e, o ti subu sile yakata, nibe lo ti jewo fun won pe oun ti mu majele, to si tun  je ki won gbo ohun e to gba sile lori foonu e.

Aya awon eeyan ja nigba ti won gbo awon nnkan to so sinu foonu naa, ni won bas are lo gbe epo (Palm oil) lati fun un mu, ti won ni won tun lo awon ogun miran to le pa oro ose naa fun.

Won ni kani ko tete jewo pe oun ti mu ose ni, bo ya ko ba ti de orun alakeji kasiri too tu pe o ti gbe majele mu. Loju ese ni won so pe won ti sare te iya laago lori foonu lati foro naa too leti. Obinrin naa ko duro wo bata to ti sare ko soko lati loo woo mo e, se won ni obinrin kii gbo ekun omo e ko ma taji were.

Pakopako ni won ni Yusuf n wo nibi to ro kale si nigba ti iya e debe, ti won lobinrin naa tun ki oro buruku mole, to si bere sii so sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI