MC Murphy |
Ogbontarigi to tun je agba sorosoro lorileede Naijiria, Alaaji Moruph
Sorunke, topo mo si MC Murphy ti so pe isokan ati itesiwaju egbe
Freelance and Independent Broadcasters’ Association of Nigeria, FIBAN loun n wa,
nitori pe nnkan to je oun logun ju niyen.
MC Murphy soro yi lana ojo Isegun Tusde nilleese Murphy’s Place to wa
lagbegbe Ita-Oshin nilu Abeokuta nibi ayeye kan to waye ni rampe, nibe lo ti so
pe gbogbo irin toun n rin ati awon igbese toun n gbe, ki egbe naa le nilosiwaju
ni.
O ni oun kii fi be lo si pati to ba ti je okan lara awon sorosoro lo n
se MC nibe nitori pe won ko ni gbajumo nnkan ti won n se mo, oun ni won maa maa
ki ni mesan me wa lai kii se pe oun loun pe won wa sibe.
Kasnaty, Omo-Baba-Tisa ati Atunbi |
MC Murphy so pe ireje loun ko, oun ko le gba ki enikeni fi iwosi lo oun
nitori e loun se ki fun ijoba ipinle Ogun lodun ti won fun Gbenga Adeyinka lowo
kan, ti won si foun ni owo ti ko to idaji ti e, o ni Gomina lo sese wa fi kun
owo naa foun.
O wa gboriyin fun alaga egbe FIBAN fun awon ipa to ti ko gege bi alaga
ninu egbe. O ni ko tii si alaga bii ti Alawiye lati toun ti n ba alaga pade,
ipa to si ti ko, ipa rere, atipe awon olote tabi awon eeyan keeyan lo maa so pe
ki ni Alawiye.
Olori, Murphy, Osila, akekoo Mapoly |
Kii se aheso tabi oro enu lasan wipe Alawiye lo koko gbe ogbon kalenda
wa sinu egbe FIBAN, ti ko seni to ronu e latodun ti won ti da egbe naa sile
lorileede Naijiria. Okunrin naa lo si koko so opolo kale pe ki won maa fun awon
agbaagba sorosoro lami eye (Award).
Ise, ipa ati ilana ti Ogbeni Akinyemi Alatoye, Alawiye fee fi sile gege
bi alaga FIBAN kii se eyi to see gbagbe titi lai ninu egbe naa lorileede yi.
Osila ati Alawiye |
Olojo ibi ojo naa, Omo Baba Tisa nigba toun naa dupe lowo awon ololufee
to wa sibi ojo ibi naa nitori pe bi kii ba se ife ti won ni soun, oun ko ni ri
enikeni. Bakanna lo so pe ko si ninu eje oun lati maa sayeye ojo ibi, sugbon
iyawo oun lo pon ni dandan foun pe a fi koun maa se e.
Eniola Sodiya, Elekeru ati Kasnaty |
O so pe lodun to koja loun le so pe ayeye ojo ibi oun bere nitori pe iyawo oun lo se keeki toun ko mo, sugbon pelu gbogbo wahala tawon se lojo naa, oun ko ranti je keeki naa, pelu ija loun fi je keeki leyin ojo keta.
Bee lo tun dupe lowo MC Murphy lori awon ipa to n ko nigbesi aye oun
nitori pe oun leni to maa koko mu oun wo ileese radio OGBC nigba toun fee bere
sii soro lori afefe.
Siwaju asiko yi Yeyeluwa Ibiyemi Ajadi naa ti koko soro pe eeyan daadaa
ni Omo Baba Tisa nitori pe oun ko le awon ibi tokunrin naa ti ran oun lowo.
Ore Oba mujo mukulu-muke |
Oju awon eeyan ree |
No comments:
Post a Comment