Iroyin to n lo kaakiri igboro bayii ni ti iroyin ajo kan to n gbe esin
Islam laruge lorileede Naijiria, iyen Islamic Music and Associated Nominees
(IMAN) to fee fun awon ogbontarigi lawujo lebun Ami Eye, Awoodu lojo Eti Fraide
ojo kerinla osu keje odun yi.
Seye Kehinde ati ambrose Somide |
Kii se awon meji yi nikan ni IMAN fee da lola, lara awon ti won tun fee
fie bun Awoodu da lola ni ogbontarigi olorin Islam, Alaaji Abdul-Latifu Oloto;
Ogbeni Sunday Esan, oludasile Okiki Films; Alaaja Kafilat Kaola, ogbontarigi
ninu esin Islam; Alaaji Abdul-Wasiu As-Sideeq, gbajumo olorin Islam; Alaaji
Bolaji Bello, gbajumo agborinjade; Ogbeni Dare Zaka, oludari orin; Alaaji
Musiliu Akinsanya, akapo egbe awako NURTW nipinle Eko ati Alaaja Rashidat
Omobolanle.
Bo tile je pe se ni won maa n dibo yan awon ti won ba fee fun lami eye
Awoodu yi ni, sugbon ajo IMAN to n sagbateru eto lodoodun ti wa so pe looto
lawon eeyan mewa yi maa wa lara awon ti won maa dibo yan, sugbon idibo naa ko
le da won lowo ko pe ki won ma fun won lami eye to to si won gege bi ipa ti won
n ko.
Isori-isori lawon ti won si maa n fie bun Awoodu yi da lola lodoodun,
sugbon ilana ti won ti fi da eto yi sile nipa idibo ko le so pe kawon eeyan
pataki ti won ti ya soto yi ma gba eto won.
Won ni ko si ojusaaju ninu ebun Awoodu ti won fee fun awon eeyan, atipe
laipe yi ni won yoo gbe idibo naa jade sori ero ayelujara ti won ti n seto e
lowo.
AWIKONKO tun rii gbo pe akori ayeye todun yi ni won pe ni “The Hall of
Fame”.
No comments:
Post a Comment