Won si tun
pase pe ki o ye pe ara e ni Baba Aladura olori ijo naa mo nitori o n tabuku ba
ijo naa pelu awon igbese to n gbe, eyi to lodi sofin ati ilana ti won fi da ijo
naa sile.
Ase yi
waye leyin ti awon agbaagba ninu ijo naa pe Alagba Solomon Alao lejo pe awon
igbese to n gbe ninu ijo naa lodi si ofin to gbe ijo naa duro lorileede
naijiria ati kaakiri agbaye.
Ojo
ketalelogun osu to koja ni Adajo to da ejo naa, iyen Onidajo Lawal Akapo so pe
ki Alagba Alao ko gbogbo awon eru ijo Kerubu ati Serafu to wa lowo ni kiakia.
Akapo wa
yan Baba Aladura, Alagba Adebayo Abiola lati tesiwaju gege bi Olori ijo naa, ko
si maa sakoso ijo naa pelu liana.
AWIKONKO
gbo pe ojo kejila osu kesan ni won gbe Alagba Alao pelu awon agbaagba kan bii
Alagba David Salako ati akowe ijo naa Alagba Akin Owolabi lo sile ejo nigba ti
won so pe awon gan an ni igi leyin ogba fun Alagba Alao, nitori awon gan an ni
won gba ona eru lati yan an sipo gege bi Olori ijo naa, ti won ko so je kawon
agbaagba kan ninu ijo naa mo si.
Won ni
yato si wipe won yan Alagba Alao, ona ti won gba lati yan an lodi sofin ati
ilana ti won fi n yan Olori ninu ijo Kerubu ati Serafu.
Nigba to n
da ejo naa, Onidajo Lawal Akapo so pe oun da Alagba Alao duro, ki o si yee
farahan mo gege bi Olori ijo naa atipe ki o ye pe ara e ni nnkan ti ko je, iyen
gege bi olori ijo naa.
Akapo so
pe lawon ipade tabi ibi ijosin ti won ba pe e si gege bi
olori ijo
Kerubu ati Serafu, ko gbodo lo, ko si so fun won pe oun ko ye ni eni ti won le
pe ni olori ijo naa.
Adajo naa
wa pase pe ki Alagba Adebayo Abiola tesiwaju lati maa sakoso ijo naa titi di
igba ti asiko re yoo fi pe, iyen odun mejo ti won ni so pe won maa n lo lati je
Olori ijo naa.
Bakanna lo
tun pase pe ki Alagba David Salako gbe opa akoso ijo to wa nikawo e sile fawon
agbaagba ninu ijo naa.
Siwaju si
ni won tun so pe ko si nnkan to n je ijo Sacred Cherubim & Seraphim Church
of Nigeria and Overseas eyi ti won ni Alagba Alao so pe oun je Olori fun, won
ni oruko naa ko han si ijo naa lagbaye, bi ko se pe awon kan ni won mo nipa
oruko naa.
Lati le
fidi oro naa mule lo je ki IROYIN OWURO ba lara awon to sunmo Alagba Alao soro
lojo Eti Fraide ose to koja, sugbon oun ti won so ni pe awon ko tii le so
ohunkohun bayii ayafi ti Baba Aladura, iyen Alagba Alao ba de lati ilu London
to lo lose yii.
Won je ko
ye wa pe ose yi, leyin ti Baba Aladura ba de lawon yoo to mo igbese tawon yoo
gbe yala lati pe ejo kotemilorun tabi soro fawon oniroyin.
No comments:
Post a Comment