Idunnu ti subu lu
ayo awon awako patapata nipinle Eko bayii nigba ti Gomina ipinle naa, Akinwunmi
Ambode so pe oun ko fee ri awon osise ajo to n ri si yi ye oko wo, iyen ajo
Vehicle Inspection Officers, VIO.
Gomina Ambode |
Gomina Ambode soro
yi lojo Isegun Tusde to koja yi lakoko to lo si afara oloke fawon elese to wa
lagbegbe Berger nibi ti ipinle Eko ati Ogun ti paala. O ni oun ko fee ri awon
osise ajo naa mo.
O so pe awon osise
naa maa n da kun sunkere-fakere awon oko lopopona kaakiri ipinle naa, paapaa
lorileede yi, o ni ijoba oun ti n gbe igbese ona igbalode lati maa mu awon
awako ti won ba wa iwakuwa tabi awon awako ti iwe won ko ba ti pe.
O ni igbese naa lo
maa je kawon mo iye oko oko to wa nipinle Eko nipa iforuko sile won, bawon
awako se gboro yi lenu Gomina Ambode ni won fo soke, ti won gbe ilu, ti won si
bere sii jo kaakiri wipe awon ti bo saye.
Ambode tesiwaju pe
kii se pe awon ona igberiko nikan ko loun ko ti fee ri awon eeyan naa mo, bi ko
se awon opopona nla pelu lo ko ti fee ri won mo. O wa sapejuwe agbegbe Ojodu si
Berger gege bi agbegbe to nilo abojuto daadaa nipa oko wiwa.
No comments:
Post a Comment