Oloye Ebenezer Obey-Fabiyi |
Awon ojise
Olorun bii Pasito Enoch Adeboye ti ijo Ridiimu, Bisoobu Wale Oke to je igbakeji
aare PFN; olori ijo CAN tele, ayo Oritsejafor ni won wa nibi ayeye ojo ibi lojo
naa lati gbadura fun Oloye Ebenezer Obey, ti won si fi oro iyanju boa won
eeyan.
Awon Oba
alade bii Ooni Ile Ife, Ogunwusi; Alake tile Egba, Oba Adedotun Aremu Gbadebo;
Osile ti Oke Ona, Oba adedapo Tejuoso. Iyalode ile Yoruba, Alaba Lawson naa
jokoo nibi ayeye naa.
Bakanna ni
awon Gomina tele nipinle Ogun bii Oloye Olusegun Osoba ati Otunba Gbenga Daniel
ko gbeyin nibe nigba ti awon oloselu bii Senato Lanre Tejuoso; Onarebu
Mudashiru Obasa to je olori ile igbimo asofin nipinle Eko; Ishola Adekunbi,
olori ile igbimo asofin ipinle Ogun naa wa nikale.
Awon
olorin igbagbo bii Mama Bola Are, Funmi Aragbaye, Yinka Ayefele, Tope Alabi.
Atawon agba olorin bii King Sunny Ade, Salawa Abeni, Alabi Pasuma, Dele
Abiodun, Adewale Ayuba, Sefiu Alao, Haruna Ishola, Tony Okoroji, Sunny Nneji,
YK, Ruggedman atawon min in naa wa nikale.
Lakoko
ayeye naa ni Gomina Ibikunle Amosun ti seleri pe oun yoo se eto bi won yoo se
ka ile kan to je pe awon orin Ebenezer Obey Fabiyi atawon agba olorin miran yoo
se wa nibe to je pe yoo da bi ibi igbafe fawon eeyan lati wa maa gbafe.
Amosun so
pe boun ba ji laaro, orin Obey loun yoo koko gbo koun to lo si ofiisi nitori pe
o kun fun ogbon, imo ati oye, bakanna lo kun fun opolopo imoran ati iwaasu ti
ko se e ko danu. Bee lo tun so pe igbakigba toun ba lo silu Oyinbo loun maa n
ri awon orin Ebenezer Obey, eyi lo je koun mo daju pe kii se awon omo Naijira
nikan ni won n jegbadun e, awon oyinbo gan an daamo.
Siwaju
akoko yin i Aare teleri lorileede yi, Oloye Olusegun Obasanjo ti gbosuba kare
fun olojo ibi naa pe opo awon orin e lo se oun lanfaani lati se aseyori laye,
paapaa lakoko to wa gege bi aare nigba ologun ati ninu ijoba alagbada.
Obasanjo
so pe, boun baa n ronu, orin Obey loun maa n gbo lati fi pa ironu oun re titi
digba toun yoo fi gbagbe sun lo.
Pasito
Adeboye naa soro, o so pe, igba akoko toun yoo fi ogba ijo Ridiimu sile lati lo
sibi ayeye niyii, atipe o ni bo se je. O loun le so pe asiko kan naa loun ati
Oloye Ebenezer Obe Fabiyi jo gba Jesu gege bi Olugbala won, atipe opo awon orin
e lo ti se oun naa ni anfaani to po repete, to si je koun naa wa lori ijokoo.
No comments:
Post a Comment