Gomina Ajimobi tun de o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 31, 2017

Gomina Ajimobi tun de o

O lodun to m bo loun yoo so eni toun fee gbe agbara ipinle Oyo fun
 
Gomina Ajimobi
Gomina ipinle Oyo, Senato Abiola Ajimobi ti so pe oduun to m bo, iyen odun 2018 loun yoo so eni ti yoo gba ijoba ipinle naa lowo oun nitori pe oun ti mo eni naa, sugbon asiko ko tii to lati soo fawon eeyan.

Gomina Ajimobi soro yi lojo Aje Monde to koja yi nibi ayeye ayajo ojo isejoba awaara ati odun kefa gege bi Gomina ipinle naa.

O ni kawon omo ipinle naa lo fedo lori orooro nitori pe awon bii marun to kaju osuwon loun ti ri lati gbe ijoba fun un, sugbon asiko naa ko tii to lati foju won han nitori pe ona si jin sigba ti saa oun yoo pari.

O leni to ba fee gba ijoba lowo oun gbodo je eni ti kii beru, to si ni awon nkan amusoro lara, to ni igboya, eni to ni ipa ati akitiyan, ati eni to setan lati fun awon araalu ni nnkan ti won n fe.

Bakan naa ni Gomina Ajimobi tun so pe o seese koun dije fun ipo Senato nipinle Oyo lodun 2019 leyin toun ba pari saa eleekeji toun n se lowo yi, bo tile je pe aimoye igba ni Ajimobi ti so pe oun ko ni dije fun ipo Kankan mo leyin toun ba gbe ijoba ipinle Oyo sile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI