Kayeefi ni iku gbajumo osere tiata nni Mojisola
Olaiya si n je fawon omo Naijiria paapaa awon ololufe e kaakiri agbaye bo se je
pe leyin osu meji gbako to bimo tan ni olojo de, ti iku si muu lo.
Moji Olaiya |
Gege bi AWIKONKO se rii gbo, ipalemo fiimu
agbelewo e kan to fee jade, Iya Okomi to
fee safihan e fawon eeyan ninu osu keje to m bo yi, ko too dipe o di agbelewo
lo n se lowo.
AWIKONKO gbo pe Mojisola sese se ayeye
ikomojade omo e tuntun tan ni Toronto lorileede Canada ni, to si n palemo lati
safihan fiimu naa tawon agba osere bii Funsho Adeolu, Foluke Daramola atawon
min in ti kopa ninu e faraye nilu Eko.
Ohun ti a gbo nipa iku e ni pe ale ana
ojoru Wesde to je osu meji geerege to bimo e tuntun, ni won so pe aisan okan
tawon oloyinbo n pe ni Cardiac Arrest gbemi e lojiji.
Osibitu kan ni Toronto lo dake si leyin tawon dokita ti da duro o ni lati se suuru lodo won nitori aisan to n yo lenu naa. Baba e, Victor ko tii ri owo ti won ni ki won lo mu wa san ko too dipe olojo de.
Osibitu kan ni Toronto lo dake si leyin tawon dokita ti da duro o ni lati se suuru lodo won nitori aisan to n yo lenu naa. Baba e, Victor ko tii ri owo ti won ni ki won lo mu wa san ko too dipe olojo de.
Bo tile je pe ironu ti iku awon agba
osere meji Olumide Bakare ati Pasito Ajidara lo si wa lokan awon eeyan bayii,
sugbon eleyi tun je kayeefi nigba tiroyin naa tun jade sita pe Moju Olaiya naa
tun ti ku.
Ojo eti Fraide ojo ketadinlogun osu keta
ni Moji Olaiya bimo ni nnkan bi aago mejo asale, leyin odun kan to pade oko e
tuntun to fun un loyun. Ko fee bimo naa si Naijiria lo je ko gba Canada lo lati
lo bii si.
Moji ati omo e |
Bi e o ba gbagbe, odun 2008 ni Moji
pade oko e akoko, iyen Okesola, sugbon igbeyawo naa ko pe ko too tuka nigba ti
won lokunrin naa ko fi gbogbo ara gba omo ti Moji ti bi tele gege bi omo ti e, wahala
yi lo tu won ka.
Mojisola to je omo gbajumo olorin
takasufe nni, Victor Olaiya ni won bi lodun 1975, to si je pe odun mejilelogoji
lojo ori e bayii.
Ko lonka lawon fiimu agbelewo ti osere
tiata yi ti kopa ninu e, nigba to je pe fiimu olose-ose kan to je ti Wale
Adenuga, iyen Super Story lodun 90s lo gbe Moji Olaiya jade sita faraye ko too
fi gbogbo ara wonu fiimu Yoruba.
Lara awon fiimu oloyinbo ati ti Yoruba
to ti kopa ninu e ni No Pain No Gain,
Nkan Adun, Agunbaniro, Sade Blade, Omo Iya Meta Leyi atawon min in. O si ti
gba orisirisi ami eye oserebinrin to dara julo.
Moji ati omo e apakeji |
Oludasile Best of Nollywood Awards,
Seun Oloketuyi naa tun jeri si iku Moji lori Instagram.
Aheso to tun n lo nigboro bayii ni eyi
ti won n so pe o seese ko je pe ilu Canada ni won maa sin Moji Olaiya si nitori
ti won so pe o si ni iya to je agbalagba atipe nile Yoruba eewo ni ki obi foju
ri oku omo e.
Gbogbo bi nnkan ba tun se n lo si ni
AWIKONKO yoo tun maa mu wa fun un yin lati ka a.
No comments:
Post a Comment