Gomina
ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele fayose ti gba Aare orileede yi, Ogagun Muhammadu
Buhari lamoran pe ko kowe fipo sile gege bi Aare bo ba mo pe oun feran orileede
yi tokan-tokan.
Fayose
soro yi nilu Eko lojo Isegun Tusde to koja lakoko to n bawon akoroyin soro lori
ipo ti orileede Naijiria wa, paapaa isejoba Aare Buhari, pelu ipo ailera to wa.
O
so pe gbigbogun ti iwa ajebanu ko da lori sisawari owo rabati ti won n doju ko
lo, bi ko se pe ki o se awon nkan to ye lasiko to ba ye.
Bakanna
ni Gomina Fayose so pe isejoba Aare Buhari paapaa egbe oselu APC ti kuna laarin
odun meji to fi wa nibe, o ni ko si eyi ti won muse ninu awon ileri ti won se
fawon omo orileede yi lakoko ipolongo idibo lodun 2015.
O
so pe eni ti ara e da saka to le sise losan loru lati koju awon isoro ati
ipenija ti orileede yi n koju lasiko taa ni orileede Naijiria nilo lati fi se
olori, kii se to je foniku-foladide. O ni igba wo la fee se gbogbo irinajo
okeokun da.
Bee
lo so pe igbakeji Aare, to tun je adele Aare lowolowo bayii ko lase Kankan to
fee pa leyin Aare funra e. Oun gang an lo ye ko so ipo ti ilera ara e wa fun
wa, kii se awon amugbalegbe e.
No comments:
Post a Comment