Eyi ni bi Olumide Bakare osere tiata se ku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 23, 2017

Eyi ni bi Olumide Bakare osere tiata se ku

Latigba ti iku gbajumo agba osere yi, Olumide Bakare to filu Ibadan sebugbe ti ku lojo Abameta Satide ojo kejilelogun osu to koja, April lawon eeyan ti n woye bi awon ilumooka osere meji nni, Pasito Ajidara ati Moji Olaiya naa tun se wole niwaju iku lati juba e.

Orisirisi iroyin lo si ti jeyo latari iku to pa Olumide Bakare, eni odun marundinlaadorin (65years), eyi to tun sina fun iku Pasito Ajidara ati Moji olaiya laarin osu meji sira won.

Gege bi AWIKONKO se gbo, opa to n gbe eje kaakiri ara Bakare ko fi bee sise daadaa mo, to si tun je pe awon isan ati opa to n gbe ounje kaakiri ara e naa pelu ikuu to pa. Nigba to maa ku laaro ojo naa, se ni won lokunrin naa deedee subu lule, ki won too sare gbe e lo si osibitu, sugbon epa ko boro mo.

Bo tile je pe enikan to sunmo Bakare nigba to n soro lori bi okunrin naa se ku, o so pe won ti sise abe fun, to si ti ye e, won lo si bawon eeyan soro, sugbon o ni leyin wakati meji ti won pari ise abe naa lo dagbere faye.

Lodun to koja, osibitu UCH (University College Hospital) to wa nilu Ibadan la gbo pe Olumide Bakare wa fun bii osu meloo kan nigba ti won sayewo e pe awon nnkan je ki ounje da lara e ko sise daadaa mo, ti won si se itoju to ye fun ko too dipe won yonda e pe ko maa lo sile.

Latigba ti won ti yonda e ni UCH ni ko ti fibe e lo si oko ere tiata daadaa mo nitori ailera ara e, bo tile je pe awon osere egbe e si n bebe pe ko wa kopa, sugbon agbara e ko gbe awon ipa ti won fi si pe ko wa ko.

AWIKONKO gbo pe aisan to seku pa Olumide Bakare ti wa lara lati odun 2013, to si je pe ko le se ko ma lo si osibitu lati lo ri awon dokita leekan laarin osu meji latigba naa, nitori o gba wipe ilera loro atipe awon dokita maa n gbawon eeyan lamoran pe o dara ki a maa se ayewo ara wa.

Iyalenu lo tun je pe lodun 2014 nigba ti iroyin ailera e gba ilu kan nigba naa, opo lo koko ro pe okunrin naa ti ku, sugbon lesekese lo ti so pe iro nla ni, oun o ku o, nitori pe oun lo sise loke oku ni.

Igbagbo awon eeyan nigba naa ni pe okunrin naa lo si orileede United State lati lo gba itoju, o si ku sibe, sugbon nnkan tokunrin naa so pe ise toun ti gbowo e loun lo fun kii se pe ohun lo gba itoju rara nitori pe kokooko lara oun le.

O ti e gbawon oniroyin orisirisi laaye lati foro wa lenu wo, to si tun n je ko ye won nigba naa pe oun bebe tabi beere owo lowo enikeni wipe aisan n se oun, ki won da owo foun lati lo si oke okun fun itoju.

Bakare so pe ko ti e si aisan kan lara oun to nilo itoju atigbadegba.

Sugbon ninu osu keji odun yi loro yi pada nigba ti aisan yi tun dide leyin ti odun to koja tawon dokita osibitu UCH ti yonda e pe ara e ti ya, o kan nilo lati dekun ise agbara, Bakare mo ohun ebe sawon omo Naijira lati dide iranlowo owo foun.

O so pe ki won ma je koun ku sinu aisan naa, o ti e tun pe awon wooli ati aafa to ni emi Olorun lara lati tun wa gbadura fun yato si iranlowo owo to nilo nigba naa.

Iyalenu lo je pe yato si milionu kan naira ti won ni Bakare tin a lori ailera e, nigba naa, egberun lona ogbon lowo to n san fun itoju ara e ni osibitu to wa lojumo.

Osise ileese telefisan ijoba apapo, NTA ni tele, Oloye Koko (Chief Koko) ni won maa n pe nitori ipa to ko ninu fiimu olose-o-ose kan to maa n se, ti won pe ni Oluwa Langbe Lodge.

AWIKONKO gbo pe omo merin ni Olumide Bakare bi; awon naa ni Olabode toun je ojise Olorun ni orileede United States; Oluwamayowa toun naa n sise adani nilu Eko; Oluwatofunmi toun je akeko jade ni fasiti ipinle Ekiti ati Halimat toun naa si n kawe lowo

AWIKONKO tun gbo pe Olumide Bakare tun je okan lara awon to lewaju ninu fiimu oloyinbo kan, Doctor Bello ti Tony Abulu se, nibi ti awon ilumooka osere bii Genevieve Nnaji ati Isaiah Washington to je osere ile Amerika ti kopa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI