Erin keekee ni fasiti FUNAAB - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 18, 2017

Erin keekee ni fasiti FUNAAB

Titi di bi a ti n koroyin yi loro Ojogbon Olusola Oyewole to je giwa ile eko giga ti Ogbin iyen Federal University of Agriculture Abeokuta, FUNAAB si n je iyalenu fawon osise atawon akeko ile eko giga naa, paapaa awon to n gbo boro naa se n lo si.

Ojogbon Oyewole
Bi e o ba gbagbe, lose to koja ni ijoba apapo da Ojogbon Oyewole ati Ojogbon Daramola ti fasiti FUTA nilu Akure duro latari esun ikowoje ti ajo EFCC fi kan won, ninu atejade ti Dokita Adamu ti ajo to n ri soro ile eko giga lorileede yi fowo si lojo kejo osu yi to si je pe ojobo Tosde ose to koja lo te won lowo pelu ase minisita foro eto, Adamu Adamu.

Sugbon lojo Aje Monde to koja yi nibi tawon osise naa ti n ronu ona ti won le gba lati tesiwaju ise ile eko naa ni won ti sadede ri Ojogbon Olusola Oyewole to wole sinu ofiisi e.

Iyalenu lo je fawon eeyan naa nitori ohun ti won koko ro nipe Ojogbon Oyewole fee ko gbogbo iwe owo e ti won pase pe ko ko feni to tun je bi oga leyin sile fun, sugbon oro ko ri bee nigba ti won rii ti Oyewole pe awon kan pe ki won wa, to si towo bo iwe owu osu awon osise patapata nile eko naa.

Seni gbogbo won bere sii woju ara won, tawon kan si n bu serin ninu bo tile je pe ko seni to to bee lati ri erin naa jade sita bi won ko ba fee fise won sere, lai je pe won ti ri ise si ileepo, iyen Filling station.

AWIKONKO gbo pe Ojogbon Oluyemisi Eromosele to je igbakeji giwa ile eko naa lo ye ki Ojogbon Oyewole fa awon iwe ase atawon nnkan min in to wa nikawo e le lowo lati maa ba ise lo nibi to baa de.

Lara awon nnkan miran ti won ni Ojogbon Oyewole tun se gege bi AWIKONKO se rii gbo nipe o tun fowo si awon owo ajeele awon osise atawon owo ti won ti je sile tele pelu awon owo ti won fee fi se ayeye awon alakoso tuntun ti won sese yan, iyen Governing Council.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI