Emir
tilu Kano, Sunisi Lamido Sanusi ti gboriyin fun okan lara awon oludije fun ipo
Gomina ipinle Ogun lodun 2015, Otunba Olarotimi Paseda fun akitiyan e nipa mimu
isokan ati alaafia wo aarin ilu paapaa orileede Naijiria.
Emir Kano, Ottunba Paseda atawon oloye nilu Kano |
Emir
soro yi lakoko ti Otunba Paseda atawon isongbe e sabewo karaole si aafin e to
wa nilu Kano l’Ojobo Tosde ose to koja, nibe lo ti sapejuwe Paseda gege bi eni
to see mu yangan lawujo, ati eni to se e fa kale gege bi asoju orileede lawon
orileede kaakiri agbaye.
O
so pe ti a ba n so nipa awon to n gbe asa ile e, paapaa asa ati ise Yoruba
laruge, Otunba Paseda je okan pataki ninu won, eni to si yye lati fi se oju
orileede lagbaye, to si je pea won ipa to ti ko ko see fowo ro seyin.
Lakoko
abewo naa lawon eya Awusa (Hausa) to n gbe ipinle Ogun ti fi Otunba Paseda han
Emir Sanusi gege bi Garkuwan Hausawan nipinle Ogun, iyen oye ti won fun gege bi
eni to nife awon eya to ku, paapaa awon eya Awusa.
Emir
Sanusi so pe looto ni won ko fi ojusaaju fun Otunba Paseda loye Garkuwan nitori
pe iroyin bo se n fowosowopo pelu awon eya Awusa nipinle Ogun ko see gboju fo
da, o si ye kawon da a lola repete.
Otunba Paseda ati Emir Kano |
O
loun ko kabamo pe oun fi oye naa ta Paseda to je omo bibi ilu Ijebu naa lore,
eni to n fi iwa omoluabi e han sawon eeyan, paapaa awon araalu e, to fi mo awon
eya to ku lorileede yi, ati nile Adulawo, iyen Afrika.
Emir
Kano wa lo akoko naa lati gba Otunba Paseda lamoran wipe ko rii daju wipe o n
yoju silu Kano lakoko to ba, paapaa nigba ti won ba n se ipade awon oloye,
nitori pe oye naa je okan pataki lara awon oye nile Awusa, ko si ri daju wipe
ko si ipo oye naa lo.
Otunba
Paseda wa dupe gidigidi lowo Emir tilu Kano, awon oloye atawon agbaagba nilu
Kano, o si seleri fun won pe oun yoo sa gbogbo agbara ati ipa oun lati rii pe
alaafia ati isokan n joba laarin awon eya Yoruba ati Awusa.
No comments:
Post a Comment