Ninu oloselu lorileede Naijiria, nitori pe laarin osu mefa to de lati wa dupo gomina nipinle Ogun lodun 2015, ipo kerin lo se nigba naa to si mu ki opo awon eeyan maa kan saara si wipe ise lo se. Ajosepo e laarin awon oloselu to ku lorileede yi ko see fenuso tan nitori pe gbogbo egbe oselu patapata lo n ba se, ti won o si soro laida. Lojo ti Otunba Rotimi Paseda ba AWIKONKO soro laipe yi nile to wa nilu Eko, o soro ile kun. E kaa awon oro to ba AWIKONKO so, paapaa nipa oselu eleyameya to n pa wa ku lo lorileede Naijiria.
Paseda |
AWIKONKO: Oruko yin?
PASEDA: Oruko
mi ni Otunba Olatunde Ritimi Paseda.
Alaroye: Nje e le so fun wa nipa bi e se je, paapaa
ipo yin lorile ede yii?
Paseda: Emi
ni asiwaju egbe oselu Unity Party of Nigeria, UPN kaakiri orile ede yii. Mo gbe
apoti idibo gegebi gomina ipinle Ogun lodun 2015 labe asia egbe oselu UPN.
AWIKONKO: Ti a ba ni ka wo, opo awon oloselu lo ti
kogba wole paapaa awon oludije ti e jo gbegba apoti idibo lodun 2015, eyin
nikan lo je pe e si wa nita lowolowo, se kii se pe ti imurasile idibo odun 2019
lo faa ti e si fi wa nita di akoko yii?
PASEDA: Bakan
meji ni. Akoko ni pe gbogbo nnkan to je mo anfaani fawon eeyan lo je mi logun,
lati maa wo awon nnkan to n sele laarin ilu ati awon nnkan to n sele nipa nnkan
ti ijoba nse. Oro awon eeyan je mi logun
paapaa awon araalu mi atawon osise ijoba. Eleekeji ni pe, gbogbo wa la mo
pe ibere kii se onise a feni to ba foriti de opin. O di dandan nigba ti a ti se
leekinni ti a gbegba oroke, 2019 tun nbo, ti a si ni eto ti a fee se, o di
dandan ki a duro lati bere si nii gbe igbese lori bi o se maa seese fun wa
lodun 2019.
AWIKONKO: Nje esi eto idibo to koja lo ko mu ifaseyin
ba yin paapaa awon omo egbe oselu yin?
PASEDA: Ko si
ifaseyin tabi ikunsinu kankan, won ni owo tomo kekere ba koko pa, akara lo maa
fi je. Nnkan ti agbalagba n ri lori ijokoo, tomode ba gun akaba, won ni ko le
ri. Idibo 2015, emi gege bi enikan mo wipe, a se daada, sugbon osu mefa la ni
lati fi gbaradi fun idibo tawon mi in fi odun merin gbaradi fun. Ninu osu mefa
naa, a gbiyanju nnkan taa le se lati ko awon eeyan jo. Sugbon o seni laanu pe kii se gbogbo ibo to je ti wa ni won ka fun wa.
Ti a ba ni ninu gbogbo egbe oselu to wa nipinle Ogun, ti egbe to jade laarin
osu mefa si se ipo kerin laarin won, mo ro pe o ye ka gboriyin fun iru egbe
oselu bee pe o gbiyanju nitori pe awon kan wa ti won ti ja seyin tipe. Ko si
ifaseyin kankan nitori pe a mo nnkan ti a fee se. Mo mo pe ki eni to ri je ko
fun eni ti ko ri je, ohun gan gan lo se pataki. Emi wa lati wa pa ise da ni. Lati rii daju pe gbogbo awon nnkan to ku
die kaato, to nje awon eeyan niya, ka wa iyanju si. Won ni ti iwaju ko ba
see lo, ka pada seyin. Eyin yen gan-an ni mo fee pada si. A o le lo siwaju mo
toripe won ti da gbogbo e ru, won ti baa je patapata, ka pada si nnkan ti a mo
lati le fi tun iwaju se pada.
AWIKONKO: Ki ni
ona eyin ti e so pe e mo ti e fee pada si?
PASEDA: O po
lorisirisi. Akoko ni pe, ijoba lo wa fun awon araalu, kii se awon araalu lo wa
fun ijoba. Ijoba ti a n wo lasiko yi lo
je pe awon araalu wa fun ijoba ni, nitori pe ijoba lo maa pase fawon eeyan pe
nnkan bayii loun fee, ko si nnkan to kan ijoba boya nnkan to fe yen te awon
araalu lorun toripe ko kan won. Ijoba ti a mo ti a fee pada si lo je pe
awon araalu lo maa so pe nnkan bayi lawon fe, ti ijoba si gbodo se e fun won.
Gbogbo awon nnkan ti won maa n se nigba aye awon Baba Awolowo, bii Town Hall
Meeting tawon oba maa n sagbateru e, nitori pe lati ayebaye, awon lo ni ase,
awon oba lo n dari awon ijoba ibile, lo n se olori ilu nigbayen lohun. Bawo le
se maa ni e fee se eto ilu, e fee se eto agbekale fawon araalu ti e o ni pe
awon lobaloba si pe ki ni won ro nipa e. Opo ijoba ibile lo ni Town Hall, to je
pe orule won ti si danu, tawon osise si wa nibe. Ise po lowo gomina, ko ye ki
gomina maa tojubo awon nnkan to n sele nijoba ibile, ise ti e ni ko maa ba
ijoba apapo dowo po, ijoba orile ede mi in dowo po lati mu awon ohun alumoni ti
yoo pese ise fawon odo wole. Boya ijoba apapo fee ya wa lowo, ba wa sepade, ise
ti gomina niyen. Ko si wa se abojuto si ijoba ibile lori owo ti ijoba apapo ba
fun won, lati woo pe se nnkan ti won fi se niyen.
Otunba Paseda |
AWIKONKO:
Sugbon, ti a ba ni ka woo, opo awon oba lo je pe oloselu ni won, won ti mo ibi
won nlo, won o si ni so ooto, nje irun nnkan bayii ko ni se akoba nipa oro Town
Hall meeting yi?
PASEDA: Ko
le se akoba rara. Otunba ni mi, oye Otunba temi kii se ti afe-aye, sugbon ti
ibile. Omo Oba ni mi. Ko si nnkan to so pe mi o ni joba lojo kan. Eni to ba mo
agbekale ori ade, to tun mo eto ilu nigbayen, a a mo pe opo ninu awon yen loo n
se ife inu won. Nigbati ijoba so pe oba o le jade lati ilu e si ilu ibomiran
lai je pe o gba ase, oba o le fi eeyan joye lai je pe o gba ase lowo gomina. E ma je ka tan ara wa, Oba to mo pe toun ko
ba ti fi ti gomina se, won a yo oun, o di dandan ko se oselu, Iberu ni.
Nigba ti a ba gbe awon ilana naa pada si bi o ti wa tele, ee ri pe awon oba gan
a se nnkan to ye ki won se. Awon oba kan si wa to je pe won a so fun ijoba pe
ko si nnkan to kan awon, nnkan to ba wun awon lawon maa se. Won a so pe kii se
owo, tabi ipo loun gbokanle, ki gomina too de loun ti njoba, ko si lase lati
yoo kuro. Awon oba kan wa bee. Ti a ba da ase pada sibi to ye ko wa, ti a fi
awon oba se asiwaju, kii se a o ni ni alaga ijoba ibile, sugbon awon to je ti
ibile, to je awon ni won mo ayinike ati ayinipada bi gbogbo nnkan se n lo, ti a
fun won ni aaye ati oore ofe, won a se nnkan to ye ki won se. Gomina a wa fun
odun merin, o n lo, alaga ijoba ibile naa a wa fodun merin, sugbon oba wa titi,
ko nibi to n lo, a fi to ba papoda. Kii se idunu awon oba ni lati maa se ibaje,
to ba je bee ni, ko soba to maa se nkan tawon araalu nfe.
AWIKONKO: Opo awon oloselu lo ti n so pe egbe oselu to
gbooro, iyen mega party lo se eto ilu daadaa, ki le ri si?
PASEDA: O le
sise, a mo sa, 'sugbon' wa n be. Ti olosa
mewaa ba ko ara won jo lati da egbe kan sile, ole naa ni won si maa ja, e ma je
ka tan ara wa. Nigba ti awon alaanu eniyan ba ko ara won jo, ko sogbon awon
naa a je nibe nitori ibi ti a ti n se ni a ti nje. Sugbon ti eeyan ba fi aanu
sowo, ere po nibe, nigbati iru awon eeyan bee ba ko awon jo, o di dandan ko
seese. Nigba temi koko bere, mo je ko ye won pe emi o se oselu eleyameya,
eni to ba fe ni ko tele mi, eni ti ko ba fe, ko pada leyin mi. Ko seni ti mi o
le ba se. To ba ti je awon oloselu to se daada ni won fee gbe egbe nla po, mo
setan lati bawon se. A fi ka sora lati ma se ko awon eni buruku mo awon eniire.
Awon egbe kan wa to je pe won bere ni daada, afigba tawon kan wole ko to di pe
tara won ni won mo. Osise ko ba ma rowo osu gba, awon eeyan o ba maa ku
lojoojumo, ko si nnkan to kan won. Won o fi annu se ijoba. Awon orile ede toku
ti a n wo, aanu ni won fi n se ijoba ti won. Ki won to gbe igbese kan, won a wo
ti mekunu. Awon oloselu won a ri je, araalu naa a ri je, eeyan le ma le je
obokun, sugbon, a je eja.
AWIKONKO: Kini ojuwoye yin nipa ayipada ti ijoba to wa
lode bayi n pariwo nipa ara to n ni awon araalu. Se o digba tawon araalu ba
bere sinii fehunu ita gbangba han. Ki ni ero pe o le je atunse?
PASEDA:
Amokun reru, a ni o wo lori, e o wo isale. Ti a ba fee so tooto, gbogbo nnkan
ti a ba ara wa ninu e yi, ti a n jiya e yi, kii se ejo Buhari. Igba wo lo de
be? Nnkan ti baje tipetipe, lateyin wa, to si tun n baje si. Won ni ko bi a se
le tun nkan se ti ko ni ni awon eeyan kan lara. Tibi tire la da ile aye. Ko si
bi a se fe se nnkan ni daada, ti awon kan ko ni fara gba iya e. A n jiya ki a
le jere ni. Ko si bi Buhari se le se atunse yi laarin osu kan, odun kan paapaa,
ko seese. Sugbon awon igbese ti Buhari n gbe yen, igbese to dara ni, o si nira.
Laipe yi ni won sope won fun NNPC ni aaye to po nibi epo, awon kan so pe
ojusaaju, sugbon kii se bee. Ojusaaju yen, irorun fun awon mekunu ni nitori
NNPC ko le ta epo koja 86naira ni lita kan. Awon ile epo kan wa ti won nnta epo
ni 180, 200 losan gan gan. Ti epo ba po ni NNPC, ero maa dinku lawon ile epo
aladani to n ta ni owo goboyi. Nnkan ti mo ri ninu awon igbese Buhari ti mo ri
pe o ku die kaato ni pe, oo le diju koo da omi too fi we fomo, basia too fi we
fomo atomo danu. Ipele lo ye ki Buhari se gbogbo awon igbese to n gbe yen. Akoko,
o ni o fee so oro epo di irorun fun mekunu, o gbodo koko fun mekunu ni akiyesi
nnkan to mAa sele lola sile lonii. O ye ko ti so pe bi apeere, iresi, ojo bayii
ni ko fi ni wole mo nitori naa ati si boda sile, kawon eeyan ti wa ni
imurasile, won a ti maa ko ounje wole ki irorun le deba won. Sugbon Buhari ko
se bee. Awon to so pe oun n tori e se nnkan wonyii lo n jiya lowo bayii. Awon
to fee yo kuro nidi jegudujera yii, to ba pe baagi iresi kan ni egberun kan
dola, won a ra, won a je, won a tun da ninu e nu nitori pe owo wa, sugbon se
awon mekunu le ra? Eyi ti mo le so pe o se to da ni pe, won ti bere sii fo epo
lorile ede yii, ko si ijoba to dan wo to rii se, tori awon ti ko ni je ko seese
po ju awon to fe ko seese lo. O tun fun awon onileese adani laaye ti won le se
ileese ti won ti n fo epo loni kereje, lati wa gba iwe ase. To ba ya, epo maa
po debi pe gbogbo wa maa gbagbe iya ti a ti je seyin. Ani lati ni suuru nitori
won ti ba orile ede yi je lati odun to po seyin.
AWIKONKO: Nje e ro pe awon iri ajo Buhari sawon orile
ede kaakiri le so eso rere kan?
PASEDA: Ti ko
ba rin awon irin ajo yi, a o le de ibi kankan lorile ede, oju kan soso la maa
wa. Wipe Buhari nna owo lati rin irin ajo, o di dandan ki eni to ba fee jade wo
moto, paapaa olori oko, o ni lati ko awon eso e dani. Eekeji, se eni teeyan fe
baa da owo po, ko ni lo baa sepade po ni? Se ti a ba n wa nnkan lodo enikan, se
ka jokoo sile pe ki won waa ba wa ni? Ko seese, a fi ko lo ba won. Fun
idagbasoke orile ede Naijiria ni, ati lati dekun iwa ajebanu lawon igbese to n
gbe. Eni to ba n wa nnkan lo ye ko maa sare kiri. Awon owo ilu ti awon oloselu
ti ko lo soke-okun, gbogbo awon ibi ti won kowo pamo si, ona bo se maa ri awon
owo naa gba pada lo n wa nipase awon irin to n rin. Ko tii gbe nnkan to fee se
jade ni, won ti mo awon to ti je orile ede yi run, won o ti fee maa daruko won
ni. Awon ilu ti won nkowo wa pamo si ni won nlo yen. Ni orile ede agbaye, orile
ede Amerika lo lagbara ju, Russia tele, sugbon ida idamokandinlogorun awon omo
orile ede Amerika ati Russia lo n gbe orile ede China kaakiri. Opo nnkan ta n
lo lagbaye paapaa lorile ede yii lo je pe China lo ti n jade. China je orile
ede to tobi ju nipa idagbasoke ileese teeyan le ronu nipa e. Ti n ba de ipo
paapaa ipo gomina ipinle Ogun, emi naa a jade lati lo wa awon to le wa ba mi fa
awon odo ilu lowo soke, nitori ni China ti a n so nipa e yii, awon odo lo n se
ise owo yii ju, nidi ero alagbeka, awon odo le maa ba nibe. Eni to ba n wa
nnkan lo n sare kii se eni ti won n lo ba fun nnkan. Ti won ba so pe ki won ko
awon orile ede ti Olorun feran ju, ninu meta, orile ede Naijiria wa ninu won.
Somalia ko to ida meta orile ede wa ti won ri isoro kekere lasan ko to di pe
won fon ka, titi di oni, won o ti yanju oro won. Ilu to n na iju iye to n ri
gba lo, ilu naa maa fo gbeyin ni, sugbon orile ede yi ko ri bee nitoripe Olorun
feran wa. Owo ti a nna ti poju, ojoojumo ni a n je gbese. Epo ti a si fi
nnduro, to ba ya, epo wa o ni to nnkankan mo. O ye ki oju ti wa nitori pe isana
to kereju lo, orile ede China ni won ti n ko wole, gbogbo nnkan ti a le fi se
isana lo wa lorile ede yii.
AWIKONKO: Leyin ayeye ogoji odun ipinle Ogun lo ti je
pe won ti pa awon akanse ise ti won so pe won n se ti, se ijoba la ni nipinle
Ogun yi abi ki le fee so si?
PASEDA: Oro
ipinle Ogun, se lo dabi bi onigba ba se pe igba e. Igba se bo se wun e ni oro
ipinle Ogun, igba gbese lo maa je ku, igba ma fun araalu je, nnkan to pe igba e
ni won baa gba. Awa la so pe nnkan to wun wa niyen, toripe won o fi tipa tipa
mu wa. Eni to ba je olori oko, ti awon to ba yii ka ba je eeyan buruku, ko si
bo se le wu ko ri, o maa sina saa ni. Toripe bi Olorun se da wa, ko seni ti won
maa gbe gun ori aleefa ti ko ni sise. Yala ki ipo yen gun tabi ki won sii lona,
tabi ko jo ara e loju. Gbogbo awon to le too sona tabi pe si akiyesi, won o po.
Awon to le so otito, ijoba ko je ki won duro toripe won o fe eni to maa gbo won
lenu. Ni temi o, ijoba la n se nida kan, ijoba ko lan n se nida keji. Ijoba
olowo la n se nipinle Ogun, kii se ijoba mekunu. A n se ijoba, sugbon gbogbo
nnkan ti a n se naa, fun anfaani awon olowo ni. Gbogbo ogoji akanse ise ti won
so pe won se, ki won wa so eyi to kan mekunu ninu e. Eyi to dabi pe o fi oju jo
ti mekunu, mekunu gan an o le de be. To ba de be, ko si nnkan to fee fi se.
Awon tori won pe repete ko po nijoba toripe ijoba ko fee awon ti won ko ni
gboran sii lenu. Bi e ba de awon ile ti won ko naa, ko si nkankan nibe, bee naa
lawon ileewosan ti ko wulo ti won ko toripe ko si noosi ati dokita ti won yoo
sise nibe. Eyi tawon osise wa, ko si irinse fun won. Gbogbo nnkan ti won maa fi
toju awon eeyan ni won maa ko fun won pe ki won lo ra, ki lo de tijoba ko le
pese awon nnkan won yii? A n se afara oloke, mi o ni ka ma se, awon afara oloke
kan wa ti ko wulo toripe latigba ti won ti se, ijamba oko dinku lagbegbe naa.
Idi niyii ti mo fi so pe ka pada seyin lati tun awon nnkan to. To ba je ki won
to bere awon ise wonyii ni won ti se ipade Town Hall ni, awon araalu a ti
pariwo sita awon ko fe biriji sawon agbegbe kan ti ko ti wulo. Won a ti pariwo pe
ki won se titi nikan, ki won se omi to ja geere fawon. Nigba aye awon Baba
Awolowo, won se kini omi igbalode to si di akoko yi bo tile je pe ko sise mo.
Leyin tigba Baba Awolowo, ko tii si ijoba to tun ko mi in nipinle Ogun. Ki lo
fee na ijoba lati fi owo se omi fawon araalu. Igba kan la n si omi ninu ile,
sugbon bayii, ko si opa to gbe omi wole mo, ka ma sese so pe ka si omi. Gbogbo
nnkan ti won le fi se omi yi lo wa nle, ki won tun un se nikan ni. Ijoba kan n
fi ojoojumo ya owo ni, dandan ni ki eni to je gbese san an, sugbon ki la fee fi
san? Ti won ba gbaa sotun sosi, ti won o ba ri bi won se maa san gbese ti won
je, owo ori araalu ni won maa yi mo. Ta lo fee san owo ori? Ijoba o ya awon kan
soto lati maa san owo ori, bi apeere awon to n gerun. Ti agerun kan ba gerun
igba naira mewa lojumo, ti won ni ko wa san owo ori egberun meji, ninu owo to n
pa lo ti maa yo owo ile, owo epo generato, lo ti maa tun awon irinse e se ati
beebeelo. Gbogbo eeyan nijoba fee maa gba owo ori lowo won paapaa awon ti ko
sise. Won o le so bee toripe gbese ti won je, won ni lati san an pada. Ibi ti
won n lo bayi ni pe, ti eeyan ko ba mu kaadi pe o san owo ori dani, ko ni le
rin loju titi. Ipinle Eko se, ti eeyan ba paaki moto segbe titi, a fi ko san
owo, ti won ba gbe moto lo, ki won to ba eni naa soro, won a ni ko lo mu iwe to
fi san owo ori wa, iru eni bee a wa sese maa sare kiri lati san owo ori tori ko
le ri moto e gba pada. Ijoba to ba gba ipo lowo ijoba to wa lode yi, to ba ro
pe oun le ri ole kan ja, aa ya lenu pe gbese lo maa ba nile, sugbon sibe aa si
fee jale naa toripe ironu wa ko ju ka jale lo. Ijoba to ba si teri si gbese
naa, aa te lowo araalu. Nnkan ti Buhari si n dojuko niyen to fi di pe o n te
lowo araalu. Opo araalu lo si ti n so pe ki won je ka pada si iwa ajebanu to ba
je pe iya ti a fee je niyii. Kii se ejo e, o teri si nnkan to gba lowo Jonathan
ni. Ko si ipo ti o soro lati se, sugbon ipinu lati se daada lo maa je keeyan le
se aseyori.
AWIKONKO: Nje e ro pe a le ya bara kuro lori oro epo
lasiko yii, nje o le seese lati so pe a fee sare ya bara?
PASEDA: Ki lo
de ti o le seese? O seese. Ti o ba si seese, o ni lati seese ni. Won ni ti a o
ba mo ibi ti a n lo, aa pada seyin. Epo ko ni won fi da Western region sile,
koko, ise agbe ni won fi daa sile to si mu idagbasoke ba. Nnkan to kan wa nibe
ni pe ise agbe kii se nnkan to le bere lonii, ko si ko ere e lola gege bii
koko. A ni lati mo nnkan to wa laarin ka gbin ati ki a ka. A gbodo ronu siwaju
pe bayii la se fee se. A le duro lori nnkan ogbin nikan lorile ede Naijiria, o
seese. Sasa ni orile ede to ni iru afefe ati ile ti Olorun fun wa lorile ede
yii. Ti a ba lo sorile mi in bii Pakistan, ti e ba n rin irin ajo fun bii
wakati meji, egbe otun ati osi, nnkan ogbin nikan le maa maa ri. Sugbon lodo ti
wa n bi, igbo lasan le maa ri. Ko sigba taa ni kuro lori oro epo tori pe awon
oyinbo ti se awon moto ti kii lo epo mo, to je batiri ni won n lo.
AWIKONKO: Nipa oro owo ti oni bilionu mejo dola ti
orile Naijiria ati China towo bowe adehun e, to je pe Dangote nikan gba ida
merin ninu e, nje ko le ko wa si oko gbese ojo iwaju?
PASEDA:
Ibeere to ye ki gbogbo wa koko beere ni pe kini Dangote fee fi owo naa se?
Atipe ki ni ere ijoba lori nnkan to fee se?. E ma gbagbe pe owo ti won nna lati
fi gbe epo wa lo si ibi ti won ti n fo ti won tun maa da pada wa fun wa nibi
lati lo, o to ilopo meta. Owo to je pe ti a ba se ninu ilu wa, owo naa a lo
sile, epo a po repete. Dangote pelu awon ti won ni ileese ti won ti n fo epo.
Won o le deede fun Dangote nikan lowo laini idi pataki. O le ma je Dangote lo
maa gba owo naa ko je pe ileese miran ni, sugbon oun lo mo ona ti a le gba lati
je ki epo po to si maa se ilu lanfaani. Ajosepo ni Dangote ato orile ede yii
fee se. Ti ki baa se ko le daa ni, won o le fun Dangote lowo ko lo fi ko le
tabi fi se nnkan miin. Sugbon nnkan to fee fi se lo se koko, iyen lo sokunkun
si araalu. To ba je araalu mo ni, won le ma soro. Aare ti a ni yi ni won n pe
ni oba talaka. Ni ilu e, asiwaju awon talaka ni. Ko fi oro talaka sere rara.
AWIKONKO: Bawo ni oro egbe oselu yin, UPN?
PASEDA: UPN
tawon eeyan mo nigbayen ti di repete, o ti gbooro sii. Opolopo awon ti won kuro
ninu egbe PDP ati APC nipinle Ogun ni won ti darapo mo egbe UPN. Mo ni lati maa
so fun won pe egbe UPN ti mo je asiwaju e lorile ede yii, emi o se eleyameya. Eni to ba wa, to ri bi a se n se, ti ko ba tee
lorun, a a pada fi wa sile ni. A o ya enikankan soto. A fe awon ti won le tun
ilu wa se ki won wa gba ipo. Ti a ba ri eni to le se asiwaju ju mi lo, mo setan
lati lo jokoo, lati maa ba iru eni bee damoran. Kii se dandan. Ohun taa ba se
lonii, itan ni lola. Itan yen, ati oruko rere yen lemi n wa. Itan bi itan Baba
Awolowo tawon eeyan si ma maa so leyin ogorun odun ni mo n wa. Eni to ba mo pe
oun le se ni daadaa la n wa ninu egbe UPN. Nipa adari UPN, Baba Faseun,
agbalagba niwon, asiwaju si ni won pelu. Oludamoran ni won je nipa pe bi a ba
fee sina, ki won pe wa si akiyesi lati to wa sona. Agba lo n ri nnkan tomode o
ri. Won o si nidi oselu mo rara gege bii nnkan ti a gbo. Awon agba ti a ni
bayii lawon agba nidi oselu, iyen awon ti won ba Baba Awolowo jokoo se oselu,
merin ninu won la ti ni bayii.
No comments:
Post a Comment