Oba Nofiu Adeyemi |
Oba
Adeyemi soro yi lati fi tako oro kan to n lo kaakiri ilu wipe oun kii se Oba
Onijaye, ti won si n so pe Olu Asasin ni, ati pe ona eru loun gba lati so ara
oun di Oba Onijaye naa.
Bi e o ba
gbagbe pe losu keta odun yi niroyin kan jade nibi tawon oloye kan ti so pe Oba
Nofiu Adeyemi yee pe ara e ni Oba Onijaye ti Ijaye-Titun, wipe Olu Asasin ni
won fi je, ti won si so pe oro naa ti de ile ejo, ti Alake naa si ti dasi oro
naa.
Sugbon ni
bayii, oro naa ti foju han gege bi awon iwe eri ti Oba Nofiu Adeyemi ko sile
fawon akoroyin ni Aafin e to wa nilu Ijaye Titun lose to koja nibi ti ijoba
ipinle Ogun ti bu owo luu pe oun gan an ni Oba Onijaye tilu Ijaye titun.
Kabiyesi
so pe ija lo de ni orin di owe, nitori pe gbogbo awon to n so isokuso kaakiri
ni won lewaju nigba tawon n seto oro oloba de yi, to si je pe awon gan an ni
won lo fa oun le Alake ati Oba Agura lowo wipe oun lawon fe gege bi Oba won.
Ade Oba Onijaye |
O so pe
ilu meji lo parapo to di ilu Ijaye Titun, awon si ni Asasin ati Kukudi, nitori
pe nigba tawon de odo Alake, ni Kabiyesi so fawon pe oun ko le fi Oba je saarin
ilu mo, nitori naa ki won lo wa ilu ti won le wa lati je Oba naa si.
O tesiwaju
pe Balogun Kukudi, iyen Oloye Rasaki Obe lo lewaju lati so pe ki won mu ilu
Asasin gege bi ilu ti Oba maa wa ki won si yi oruko ilu naa pada si
Ijaye-Titun, tawon oloye toku naa si fowo si.
Oba
Onijaye tun fi kun oro e pe lakoko naa ni ileese to n ri seto idajo so pe ki
won too le fun won ni iwe eri, eni ti ade ba wa lowo e ni won maa fi je oba, to
si je pe oun gan lade naa wa lowo e nitori pe latigba ti won ti gbe ade naa de
lodun 1832 lo ti wa nidile oun.
O ni
nitori pea de naa wa nikawo oun ni ko faaye sile fenikeni lati ba oun du ipo
oba naa, atipe ni gbogbo igba ti won n da ifa pe tani ipo oba to si, oun gan an
ni ifa n toka si gege bi eni to leto lati je oba naa.
O so pe
iyalenu lo je nigba tawon pari gbogbo eto naa, ti won fohun je Oba Onijaye. O
ni ko tii ju bi osu mefa lo nibi tawon ti n se weje wemu ni ile ni enikan beere
lowo oun pe toun ba waja, tani ipo oba naa kan. Ibeere yi lo bi ohun ninu, toun
fi pariwo sita pe kawon araalu gba oun lowo awon to n robi roun.
O ni Alake
lo bawon yanju oro naa, sugbon ko tun ju bi osu meta sigba naa ni won tun ran
awon agbanipa wa ka oun mole, to si je pe Olorun lo yo oun lowo ota ibon ti won
yin foun, nitori pe osu meji gbako loun fi w anile iwosan ti won gbe oun lo.
O ni leyin
naa ni won tun mu oro oun lo sodo komisana olopaa ipinle Ogun nigba naa, sugbon
leyin awon iwe eri toun ko sile, ni Komisana naa so pe apaayan lawon eeyan naa,
nitori pe awon gan an ni odale. O so pe oun loun bawon be lojo naa nitori pe
awon olopaa ti fee ti won mole ki won sig be won sile ejo.
Sugbon o
so pe gege bi oba to n fe ilosiwaju to si n fe alaafia laarin ilu, oun ko mu
won gege bi ota, oun tun ko won mora.
O ni
orisirisi iro ni won ti pa mo oun lodo Oba Agura, eyi to si je pe Oba Agura ko
beere oro lowo oun to fib ere sii gbe igbese ti ko ye ko gbe, o ni oun setan
lati so gbogbo boro naa se je fun Oba Olaloko to ba ranse pe oun.
Ariwo ko
ReplyDelete