Lojobo Tosde ose to
koja lawon eeyan to ri gbajumo obinrin sorosoro ori redio nni, Arabinrin Toyin
Adeniji, topo mo si Queen Toyin tabi Olori nibi ale awon osere ti egbe TAMPAN
ipinle Ogun se fun oloogbe Pasito Ajidara n beere pe igba wo lobinrin naa
darapo mo egbe osere tiata.
Gbogbo kukukeke ti
won ni Olori n se pelu awon osere tiata naa lo n se won ni kayeefi pe bawo lo
se mo won, igba wo lo mo won, paapaa nigba to tun loo ba Yomi Fash lanso nibi
to jokoo si, ti won si jo n soro.
Nigba tawon eeyan
koko ri pelu obinrin kan to maa n sebi arugbo ninu fiimu tawon eeyan n pe ni
Iyaniwe, eni ti won so pe aisan gbe e pamo fungba die, ti ko fi je ko raaye
kopa ninu fiimu, se ni won ro pe o lo ba lati le je ko fona han lati le mo awon
agba osere naa.
Iyalenu lo tun je
nigba ti won pe awon osere to ti mura sile lati dawon eeyan laraya nibi ayeye
ale awon osere naa, ti won ri Olori to gun ori patako ti won ti n pafoomu, to
si wa lara awon to bawon korin, iyen awon osere TAMPAN Abeokuta South.
AWIKONKO gbo pe
Queen Toyin Adeniji ti wa lara awon osere TAMPAN tele ko too darapo egbe
sorosoro FIBAN l’Abeokuta, won ni tori owo ti ko ri daadaa ninu egbe osere naa
lo je ko yabara sidi ise sorosoro, to si ti bere sii seto lori redio kan ti won
pe ni redio molebi, iyen Family FM.
E waa gbo o, Nigba
tawon osere tiata ti Toyin wa lara won bere sii korin, se ni won ni aya e koko
bere sii ja bi won se gun ori oke, to si n beru pe koun ma lo sise, sugbon obinrin
naa koko fombu nigba ti won bere orin nitori se ni won so pe enu lo n je.
Won ni ko koko mo
orin naa, to si n jenu bi eni pe won ti jo se riasa (rehearsal) tele ni, gbogbo
bi won se n mi sotun lo n woe se awon toku lati ma je ki oka fo pe ko bawon se
riasa, sugbon nigba torin naa bere sii dun, lo ba geeti e daadaa pelu won.
E ba wa beere lowo
Queen Toyin Adeniji pe ki lo n ja laya nitori pe ko sigba to ri akoroyin ti aya
e ko nii ja boya won fee ko oro buruku nipa e ni. Se eni ti ko ba se nkan iberu
ni ko nii beru, ti ara ko si nii fu pe won fee tu asiri oun sita.
No comments:
Post a Comment