E gbadura fun Aare Buhari o – APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 15, 2017

E gbadura fun Aare Buhari o – APC

Egbe oselu All Progressives Congress, eka tipinle Ondo ti rawo ebe sawon omo orileede Naijiria lati maa gbadura fun Aare orileede yi, Muhammadu Buhari fun ti ailera e.

Akose egbe oselu naa, Ogbeni Abayomi Adesanya lo pariwo sita lakoko to n bawon akoroyin soro nilu Eko loni ojo Aje, Monde.

Bi e o ba gbagbe, ojo Aiku Sande to koja lo lohun, iyen ojo keje osu yi ni won gbe Aare Buhari lo silu London fun ayewo nipa ailera e to ni, bo tile je pe AWIKONKO gbo pe eekookan ni Aare Buhari n yoju si ofiisi ko too lo.
 
Agbenuso egbe oselu naa rawo ebe sawon omo Naijiria pe ki won lo ni opolopo suuru, ki won si maa gbadura tosan toru fun Aare Muhammadu Buhari lati le pari saa isejoba yi nipa gbigbogun ti iwa ibaje laarin awon oloselu atawon araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI