Buhari ko le kowe fipo sile o – Arewa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 21, 2017

Buhari ko le kowe fipo sile o – Arewa

Egbe Arewa Consultative Forum ti so lojo Abameta Satide to koja yi pe Aare Muhammadu Buhari ko le kowe fipo sile gege bi Aare orileede yi nitori ailera ara e to gbe e lo silu Oyinbo lati lo gba itoju.
 
Egbe naa so pe adura ni Aare Buhari nilo lowo omo Naijiria. Won ni wipe Aare Buhari ti gbe gbogbo agbara le igbakeji e, Ojogbon Yemi Osinbajo lowo gege bi ofin orileede yi todun 1999 se so o ko tumo si wipe Aare yoo kowe fipo sile.

Bi e o ba gbagbe, eni to n sagbateru eto BringBackOurGirls, Aisha Yusuf ti so fun Aare lojo Eti Fraide wipe ko kowe fise naa sile ninu atejade ti akowe egbe naa, Muhammad Ibrahim fowo si, lo ti so pe bo tile je pe kii se didun awon omo orileede ni ki Aare won maa saisan ti ko ni fun lanfaani lati se ojuse to ye ko se, sugbon kii se lorileede Naijiria mo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI