Bo tile je pe ojo Aje
Monde to m bo yi, iyen ojokejilelogun ni adajo ile ejo Majisireeti to fikale
sagbegbe Surulere nipinle Eko, Ogbeni A.A Paul so pe oun yoo tesiwaju ninu esun
ti won fi kan Ogbeni Muritala Olaniyan, eni aadotan odun.
Esun ti won fi kan
Ogbeni Olaniyan ni pe o ji foonu onibara e kan, Ogbeni Godwin Enoch ladugbo
nigba to lo ogbon alumokoroyi lati fi ji foonu naa lojo kejila osu yi ni nnkan
bi aago mesan aaro ojo naa.
Inu soobu ni won so
pe Olaniyan ti loo ba Enoch to si so pe oun fe nnkan, nibi ti won ni Enoch ti
wa n nnkan ti Olaniyan fee ra, ni o ti nawo mu foonu naa, to si tete fibe sile.
Ko tii ju iseju
meedogun ti Olaniyan kuro ni soobu Enoch lo bere sii wa foonu e, to si lo ba
Olaniyan nile pe foonu oun to mu loun wa gba, sugbon se ni won so pe Olaniyan
yari kanle pe oun ko loun mu.
Loju ese ni Enoch ti
gba tesan olopaa lo lati lo fejo sun, ti won si wa gbe nile lati lo foro wa
lenu wok o too dipe o jewo leyin bii wakati meta. Nibe lawon olopaa ti so pe a
fi kawon foju e bale ejo.
Nigba to n soro,
agbejoro olopaa, Ogbeni Christopher Okoliko to so niwaju ile ejo pe foonu ti
Olaniyan ji je egberun mejidinlogun, tawon si ti gba foonu naa lowo e. O so pe
iwa ti olaniyan hu yi lodi si ofin ole jija ninu iwe ofin ipinle Eko todun 2015.
Bo tile je pe
Olaniyan so pe looto loun jebi esun ti won fi ka noun, sugbon ki ile ejo boju
aanu wo oun. Onidajo Paul so pe oun ko ni fun ni anfaani pe ki won gba beeli e
titi ti ojo igbejo miran yoo fi waye.
Inu iberubojo lawon
ebi Olaniyan wa bayi nitori won gbagbo pe ile ejo le so okunrin naa sewon.
No comments:
Post a Comment