Sugbon
Ambali niro lo n pa
Opo lo ti n woye ibi ti oro
Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun atawon osise e yoo jasi lojo Aje Monde ose
to koja to je ayajo ojo awon osise lagbaye nitori bi won se n reti oun to fee
sele lojo naa.
Lakoko ti won n be Amosun |
Bawon kan se n so pe Amosun ko
ni foriji awon ti osise merin ti amosun loun da duro lodun to koja, bee lawon
kan ni eleyinju aanu ni Gomina Amosun, tawon kan si n so pe Ogbeni Akeem Ambali
to je olori awon osise nipinle Ogun, toun naa wa lara awon ti Amosun da duro ko
ni ni anfaani lati bawon eeyan e soro.
Lakoko ti Gomina n bawon osise
soro lojo naa lo ti so pe oun foriji meta ninu awon Tisa toun da duro pelu
ifeyinti tipatipa, toun yoo si san gbogbo owo to ba je eto won fun won. Awon
meta naa ni Dare ilekoya, Eniola Atiku ati Nola Balogun. Eyi lo je kawon kinu
opo awon osise dun lojo naa ti won si patewo fun Gomina.
Oro tun yipada nigbati Amosun
soro to tun fi “sugbon” sii pe oun ko tii le soro lori ti Oga awon osise, iyen
Ambali nitori pe okunrin naa ti gbe ejo lo sile ejo, leyin esi abajade esi ile
ejo loun yoo to le soro, nitori pe ile ejo lo ni ase lowo bayii.
Oro naa bi opo osise ninu nitori
ti won so pe ile ejo ti oro naa wa ko ni nkankan se pelu igbese ti Gomina fee
gbe, awawi lasan, ati atamo ni Amosun n wa, ti won si gbe patako sita pe afi ki
Amosun foruji Ambali, ko si daa pada senu ise.
Nigba toun naa n soro, Ogbeni
Akeem Ambali so pe kii se igbese to ye Amosun gbe lo gbe yen, nitori pe to ba
so pe oun dariji awon osise, ko ye ko tun so pe dandan ni ki won feyinti,
nitori pe awon kan wa laarin won to je pe o si ku bii odun merin si marun ki
akoko ifeyinti won too de.
O ni o ye ki Gomina Amosun naa
saanu awon eeyan lona to ba to nitori pe Olorun Olorun ti saanu oun naa lona to
po, atipe ko si nnkan tawwon omo e, tabi ebi e n fe ti won ko ni ri.
O ni awon agbaagba bii Alake,
Awujale, Olu Ilaro ti da soro naa, sugbon Amosun ko gbo siwon lenu, “Kini a se
ara wa ti a o le dariji ara wa, mo mo pe ko na Gomina ni nkankan lati dariji
gbogbo wa, nitori pe ori bibe ko ni oogun ori fifo.”
No comments:
Post a Comment