Osu marundinlogbon
gbako ni ayederu wooli, Lukman Yaya, eni odun mejilelogbon ti won lo n lo gbaju
e maa lo ninu seeli, fun ti ese ti won lo se. Ojo Aje Monde to koja yi ni Adajo
ileejo Majisireeti to wa ni Ota, iyen S. O. Banwo so pe oun ko nii fun ni
anfaani lati san owo tabi pe ko fi nkan dipo ewon to fee lo se.
Bo tile je pe ko seni
to le so pato ibi ti ayederu wooli naa n gbe, sugbon o bebe pe looto loun jebi
awon esun ti won fi kan oun.
Siwaju asiko yi ni
Agbejoro Chudu Gbesi ti so fun ile ejo pe ni nnkan bi aago mokanla aabo aaro
ojo kejo osu keji ni ayederu wooli naa se ese naa lagbegbe Joju, ni Sango. O ni
o tan Arabinrin kan, Aderibigbe Toyosi pe oun fee ran an lowo nipa isoro to ni,
to si gba egberun metadinlogun ataabo lowo e, sugbon ti ko se nnkan to loun fee
fowo naa se.
O tesiwaju pe
ayederu wooli naa tun ji foonu towo e to egberun metalelogun to je ti obinrin
naa. O lawon ese yi tapa si ofin odaran ipinle Ogun todun 2006.
No comments:
Post a Comment