Awon oni fayawo atawon kositoomu koju ija sira won ni Sango - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, May 12, 2017

Awon oni fayawo atawon kositoomu koju ija sira won ni Sango


Lojo Isegun Tusde to koja yi lawon eso asobode kositoomu koju ija siran won lagbegbe Sango Ota ipinle Ogun, eyi ti AWIKONKO gbo pe eeyan kan soso lara awon onifayawo naa ti a ko tii mo oruko e titi di asiko yi lo ku nibi ija agba meji naa.

Ohun to te AWIKONKO leti nipa ija naa bere lasiko tawon eso asobode kositoomu naa dena de awon awon oni fayawo yi ti won ni baagi iresi to to marundinlaadota, paali toki to fi meji din ni oodunrun ni won se fayawo e wole lati Idiroko, iyen ni bebe Orileede Olominira Benin.

Agbenso fun ileese Kositoomu, Ogbeni Abdullahi Maiwada nigba to n ba AWIKONKO soro so pe awon eso won ti gba eru naa lowo won, ti won si n ko won lo si oluleese won to wa ni Ikeja ipinle Eko ko too di pe awon onifayawo naa lo dena de won lati ba won ja lagbegbe Toll-gate ni Sango Ota.

O ni ere lawon eso won koko pe, sugbon nigba toro naa fee koja oju ti won fi n wo, lo je kawon naa yiju pada siwon, ti won si yinbon pa okan lara awon oni fayawo naa. O lo seni laanu pe oko Hilux tawon eeyan won gbe lojo naa, lawon onifayawo yi dana sun, ti won si tun fo gilaasi oko miran lara oko won, bo tile je pe won tun ba oko meta min in to je ti araalu je.

O tesiwaju pe lesekese ni won ti gbe awon eso Kositoomu to farapa lo sile iwosan kan to wa nitosi lati gba itoju, bo tile je pe won ko daruko osibitu naa nitori aabo ojulalakan fi n sori. O loro naa ti wa lago olopaa fun iwadi.

Abimbola Oyeyemi to je agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun nigba toun naa n so tie, o so pe laaro ojo Isegun Tusde ni waahala naa sele laarin awon oni ffayawo ati kositoomu, lakoko ti won n ko eru fayawo lo si Ikeja.

O lesekese tiroyin ti te awon lowo lawon ti ranse pe awon olopaa to wa nitosi lati lo dasi, ki won si rii pe won yanju bo ti to ati bo se ye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI