Okan lara awon gbajumo omo egbe oselu All Progressives Congress (APC) nilu
Ilaro, Onarebu Salami Ismail topo mo si Onarebu Small ti so pe inu oun ko dun
fun ipo ti egbe naa wa lowolowo bayii nitori pe awon omo egbe ko gbadun egbe bo
se to ati bo se ye atipe won ko je ere egbe.
Onarebu Small soro yi lojo Abameta Satide to lo lohun nibi ayeye oku baba e to
doloogbe leni odun metalelogorin nibi ti Alaaji Adaradenu Jamaika ti dalu bole,
ti Aafa Sheu Muhammadu Jamiu ti foro waasi bo awon alejo.
O ni nnkan to da oun loju nipe ti oga oun Senato Solomon Olamilekan Adeola Yayi ba di gomina ipinle lodun 2019, awon omo egbe naa gbodo je awon anfaani tijoba to wa lori aleefa fi n dun won lowo bayii.
O tun so pe aini eeyan to kun oju osuwon lati du ipo gomina ipinle Ogun lo n fiya je won nile Yewa, sugbon ni bayi ti Olorun ti fi Senato Yayi dawon lola, asiko lati gbajoba ipinle Ogun ti to leyin ogoji odun.
Nigba to n so idi to fi tele Senato Yayi, o so pe oun ko deede tele e bi ko se pe oun ti wo awon idagbasoke to ti mu ba awon agbegbe to ti soju fun nipinle Eko, eyi to fa a ti won fi n so pe oun lawon fe n lasiko idibo, nitori e loun se nigbagbo ninu e pe yoo se ju bee lo to ba di gomina gege bi ilu abinibi e.
O wa ro awon olori egbe oselu naa lati se atunse to ba ye ninu egbe naa kawon omo egbe le je mudunmudun to wa ninu ijoba gege bawon omo egbe naa nipinle Eko se n je e.
Bakanna nigba to n sapejuwe baba e gege bi eni to nife awon eeyan to si ko eeyan mora, o ni bo tile je pe ibanuje nla lo je foun pe baba oun dagbere faye lasiko yi bo tile je pe o ti le ni ogorin odun loke eepe, sugbon oun ko le gbagbe awon ipa to ko nigbesi aye oun atawon molebi toku. O ni asaaju rere to see tele ni baba oun nigba aye e.
Olori ebi, Alaaji Lateef Adebayo Salami nigba toun naa n soro dupe lowo awon alejo to wa lati bawon se ayeye ikeyin fun baba won Oloogbe Adebayo Salami. O sapejuwe Oloogbe naa gege bi eeyan to n fe ilosiwaju awon ebi paapaa awon araalu to ba mo.
Onarebu Small |

No comments:
Post a Comment