Laaro
Ojobo Tosde ose koja lawon ara oja Sapon nijoba ibile Abeokuta South so pe awon
ko nii gba, ayafi ki Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun se atunse lori ona ti
won fi pin awon soobu ti won sese ko, eyi ti won so pe won pin fawon.
Gomina Amosun |
Nigba ti
awon ara oja naa n bakoroyin wa soro, won so pe l’Ojobo Tosde ose to koja ni
Gomina Amosun wa pe awon oruko awon ti yoo lo soobu naa, sugbon iyalenu lo je
pe nigba ti won maa pada wa le oruko naa mo ara patako, ayederu iwe ti Gomina
fi pe oruko ni won wa le.
Won ni opo
awon eeyan ti won ko mo ri rara ni won fun lawon soobu to ye ko je tawon to ti
n taja ni oja Sapon tele, iyen awon tijoba wo soobu won. Bee ni won so pe awon
osise ijoba ni won lo gbe wa pe ki won wa maa lo soobu naa.
Iyaloja
Sapon, Daikoni Olajumoke Abioye nigba to n soro pelu iporuru okan, o so pe oro
naa su oun nitori pe gbogbo awon tawon tun le pe ni olori ninu oja Sapon ni won
ko ri soobu gba, to je wipe se ni won so fun won pe ki won lo wa ibomiran ti
won fee lo, tabi ki won lo sun sile.
Iya agba
naa so pe nigba toun gbo soro naa, nise lo re oun wa nitori pe gbogbo awon to
ti n lo soobu naa latodun to ti pe ni won ko ri soobu gba, atipe iyalenu lo je
foun nigba ti won wa le iwe oruko ti gomina Amosun pe lose to koja, to si je
oruko awon eeyan marun ni won yo kuro ninu iwe naa, to je pe oruko awon kan ti
won so pe osise ijoba ni won, ni on fi ropo oruko awon eeyan naa.
O ni oun
mo pe Gomina Amosun ko mo si nnkan to n sele naa bi ko se pe awon ti ijoba ran
ni won wa lati se awuruju naa. O so pe Soobu keji, iyen nomba 2 to je pe
Babaloja lo ye ki won fun, atipe Gomina ti pe oruko e gege bi eni ti yoo lo
soobu, naa, ko seni to le so bi oro naa se je, to fi je pe oto leni ti won tun
fun.
Iyaloja
naa wa rawo ebe si Amosun pe ko tete wa se atunse lori oro soobu naa, ko too da
wahala tawon ko lero sile laarin ilu. O ni awon ko le la oju awon sile ko je pe
awon ti won ko bawon jiya ni won maa wa je igbadun tawon fi odindi odun mefa
gbako jiya e.
Babaloja
naa, Oloye Femi Akingbade nigba to n soro so pe “Ko si igbese kankan ti a fee gbe, nitoripe Gomina Amosun ti so pe
gbogbo eni toun wo soobu loun maa fun ni soobu e pada leyin ti won ba pari, a
wa n be Gomina wa pe ko ko fun wan i soobu gege bi a se wa nibe tele. Nomba
akoko ni mow a tele, nomba ketalelogbon ni won lo fimi si loke. Kii se emi
nikan, a po bee, leyi ti ko si bojumu to.”
Bakanna lo
tun so pe won tun gbe soobu kan ti ko to eni kan soso lo, ni won tun gbe feeyan
meji ti won ni ki won jo pin. O ni awon tawon ko mo ri ti won so pe osise ijoba
ni won, ni won won tun pin soobu to to sawon fun. O lawon tawon wan i oja Sapon
mo ara won.
O ni awon
ti ranse si Gomina Amosun, sugbon boya ohun awon de odo e tabi ko debe, awon ko
le so, sugbon nnkan tawon fee se nipe ko seni ti yoo lo okan ninu awon soobu
naa ninu awon ti won pin fun, ayafi ti Gomina Amosun ba wa se atunse le e lori.
Ogbeni
Olatunji to je Agbenuso oja Sapon nigba toun naa n fibinu soro so pe odun marun
ataabo lawon fi wa ninu ojo ati oorun latigba ti Gomina ti pase pe ki won wo
soobu awon, ti won si seleri pe ki won to fun enikeni ni soobu, awon ti won wo
soobu won ni won maa koko je igbadun soobu naa.
O ni nigba
tawon lo lati lo sewadi lodo Komisana foro ise, awon ko ri fun bii wakati marun
tawon fi wan i ofiisi e, sugbon akowe e lawon ri, nnkan to so nipe ijoba yoo
gbe igbese le lori, sugbon titi di asiko yii, awon ko tii gbo nnkan latodo
ijoba ipinle Ogun.
Okan lara
awon oloja, iyen Arabinrin Bangbelu to ba akoroyin wa soro laaro ojo naa so pe
ileri ti Gomina Amosun se fawon nigba ti won wa wo soobu awon ni pe kawon
farabale nitori pe nomba tawon wa tele lawon maa gba pada, to si je pe bee ni
Gomina se pe oruko nigba ti won wa lose to koja, sugbon iyalenu lo je pe kii se
bi Gomina Amosun se pe oruko ni o se wa ninu iwe oruko ti won pada wa le.
O lawon mo
pe Gomina Amosun ko le lowo si awon iwa ti ko bojumu naa, sugbon awon ti Gomina
ran nise ni won n je isekise, sugbon sibe sibe, awon ko ni gba ki won gba
satide lowo awon, ki won wag be sande le awon lowo, eto awon lawon n ja fun.
Gbogbo
igbese lati ba Komisana foro ise nipinle Ogun soro lo ja si pabo titi di bi a
ti n koroyin yi.
No comments:
Post a Comment