Sulaiman atawon ore e |
Sulaiman Fatai, eni
odun mokanlelogun; Ayobami Alao, eni odun mokanlelogun; Yusuf Sodiq, eni ogun
odun ati Emmanuel Adeleke toun je eni odun mejidinlogun la gbo pe Osodi l’Ekoo
ni won ti maa n wa digunjale ni Sagamu ko too dipe isu dile leyin asunsu je
won.
AWIKONKO gbo pe ni
ale ojo towo awon olopaa Sagamu te won, won ti setan lati ja moto gba lowo awon
to ba ko si pampe won, sugbon awon eeyan kan to fura si won lo te awon olopaa
laago wipe ki won tete maa bo.
Gege bi AWIKONKO se
gbo nipa bawon eeyan naa se maa sise ibi won lagbegbe Interchange to wa ni
opopona Sagamu, won ni kii se moto nikan ni won maa n ja gba lowo awon eeyan,
bi ko se pe okada, owo ati dukia ni won maa ja gba, ti won si n pa awon eeyan
lekun.
Won lopo emi lo ti
towo won bo lakoko ti won ba n sise won. Bee la tun gbo pe se ni won maa n se
bi agbero, to si je pe onimoto to ba duro pe oun fee gbero lodo won ti wo gau,
ati pe won tun maa n se bi eni to n toro owo, awon to ba si duro lati saanu ti
rugi oyin, gbogbo eru owo onitohun ni won maa gba patapata, ti won a si so iru
eni bee si kolobo aye.
Nigba tawon naa n
jeri sii, Sulaiman so pe o ti pe tawon ti n jale yi, atipe airikansekan lo sun
awon de be, o ni Eko lawon ti maa n wa jale ni Interchange yen, o tesiwaju pea
won olopaa ti fee mu awon lojo kan ri sugbon, ori lo ko awon yo, lai mo pe owo
si maa te awon.
Nigba toun naa n
soro, Agbenuso olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe odaran paraku lawon
eeyan naa nitori pe opo awon araalu ni won ti pa lekun, ti won si tun ti demi
awon mi in legbodo.
O ni opelope aawon
araalu to ta DPO Sagamu, Ogbeni Moses Aduroja lolobo, ko too ko awon olopaa e
leyin lati lo koju won. Gege bo se so pe orisirisi eroja oloro bii irin tawon
kafinta ma n lo, iyen sisu; ada, obe, pana, lebe atawon nnkan ija oloro miran
toun ko le ka tan. O tun so siwaju pe Komisana awon ti pase pe kawon olopaa
digboluja, FSARS ko won lo lati tubo lo foro wa won lenu won, atipe ko ni pe ti
won yoo foju bale ejo.
O wa fi kun oro e pe,
Komisana si duro lori ileri e pe oun ko nii faaye sile gba awon odaran, tabi
awon to ba fee da alaafia awon araalu laamu nitori pe aabo emi ati dukia awon
eeyan ipinle Ogun lo je oun logun ju, toun si fe kawon araalu maa sun asundokan.
No comments:
Post a Comment