Awon osere tiata tun soro ile kun
Pasito Ajidara |
Ironu iku
agba osere tiata nni, Olumide Bakare lo si wa lokan gbogbo eeyan, paapaa awon
osere tiata kaakiri orileede Naijiria ati ni oke okun ti ko si tii kase nile ko
too di pe ajalu nla miran tun wo agbo tiata wa.
Ibeeere
tawon eeyan n beeere ni pe “igba wo ni
aisan kidirin naa ti bere, igbawo lawon eeyan to fi mo awon omo egbe e to
pariwo sita.” Ohun ti a gbo ni pe kii se pe aisan naa sese de si lara, o ti
le ni odun marun, to si ti na opolopo owo le e lori.
Beeyan
ba de ile okunrin naa to wa ni Oluwo, Abiola Way niluu Abeokuta, ko digba ti
won ba to o so, ki won to mo pe akoni pataki kan lo lawujo, bawon kan se n
sunkun, bee lawon min in parowa siyawo ati ebi okunrin naa.
Nigba to wa lori beedi |
AWIKONKO
gbo pe nirole ojo Eti Fraide, ojo kerin osu yi ni iroyin jade sita pe ara agba
gbajumo osere tiata nni, to tun je Gomina fegbe Theatre Arts and Motion Picture
Association of Nigeria, TAMPAN, eka tipinle Ogun, Ogbeni Samuel Adesina
Adesanya (JP) ko ya, o si nilo iranlowo owo to to milionu meedogun naira, gege
bi Yomi Fash-Lanso se gbe e sita, iyen lori ero ayelujare.
Ninu oro
ti Fash-Lanso ko sita naa lo ti fi akanti nomba iyawo Pasito Ajidara, Atinuke tawon
eleyinju aanu le san owo si pelu e, ti a gbo pe lesekese tawon alaanu ti ri ni
won ti n fi owo ranse sinu akanti naa, lati ran Pasito Ajidara lowo, tinu won
si n dun pe awon eeyan feran won.
Lakoko tawon TAMPAN lo sabewo si |
Laaro
ojo Abameta Satide niroyin ti kan kaakiri agbaye, nitori opo iwe iroyin, iroyin
ori ero alatagba, ileese telifisan ati redio ni won fi n fonrere pe kawon eeyan
ran won lowo lori aisan kidinrin to n yo Pasito Ajidara lenu, to si nilo ki won
gbe e lo silu Oyinbo lati se ise abe fun un.
Sugbon nigba
to di nnkan bi aago mesan abo ale oj Satide ni oro yiwo, nitori ohun ti a gbo
nipe awon osere tiata tegbe TAMPAN si wa lodo e ni nnkan bi aago mejo abo ale
ojo lati lo kii, ti won sit un gbadura fun un. Ohun ti won lo n tenumo fun won
ni wipe ki won sa gbogbo ipa won lati tete je ki fiimu ti won n ya loruko egbe
TAMPAN tete jade sita ko too pe ju.
Won ni
ko tii ju bi iseju melo kan lo tawon egbe TAMPAN kuro lodo e loro beyin yo,
tawon noosi, dokita atawon toro naa soju e bere sii forigbari, ti won n sare
soke-sodo lati doola emi, nitori ti won so pe bi Ajidara se n mi ti yato si ti
tele, eyi ti won lo o ko iberubojo bawon eeyan lojo naa.
Ile Pasito Ajidara |
Gege bi
AWIKONKO se gbo, ohun ti won loo je ki iku Pasito Ajidara ya ni Kankan ni ti
iroyin to gbo pe o n lo kaakiri igboro pe kawon omo Naijiria ran oun lowo, eyi
ti won so pe o je pataki nnkan ti ko fe laye. Ko fe ki won toro owo foun nitori
aisan to n se oun. Bo se gbo oro naa lo ba wo o pe, ohun ko le la oju oun sile
ki won ba oun loruko je.
Opo awon
eeyan ni won ba AWIKONKO soro lori iku to pa Oloogbe Samuel Adesina Adesanya,
topo mo si Pasito Ajidara, eni to je pe kekere lo bere ise tiata, ko too darapo
mo ile ise eto idajo nipinle Ogun, to si feyinti ni lodun 2015 leyin odun
marundinlogoji tawon osise ijoba maa n lo lenu ise.
Ironu dori agba kodo |
Ki
Pasito Ajidara too feyinti lo ti je alaga nile ise eto idajo ipinle Ogun, to si
daadaa lakoko to fi je alaga nibe.
Lesekese
ti iroyin ti te Yomi Fash-Lanso leti lo tun ti sare se fidio oniseju kan lati
fi kede pe Pasito Ajidara ti ku, tawon eeyan si ti bere sii foro ibanikedun
ranse sawon ebi e lati ori ero ayelujara naa.
Osibitu
kan ti won pe oruko e ni Mercy, to wa ni adugbo Panseke, Abeokuta lokunrin naa
ku si, sugbon ko to di pe o ku lo ti maa n lo se ayewo lori aisan naa, ti won
lo si ti na opolopo owo ara e le lori. Won ni okunrin osere yii je enikan ti ko
feran lati maa bebe fun owo, to si je eni to ko ara e nijanu.
Ka ni bi
aisan naa se wa lara e lo ti pariwo sita fun iranlowo owo fun ise abe ni oke
okun ni, o seese ko si wa laye titi di akoko yii sugbon nitori o je enikan ti
ko fee iwosi, ti ko si feran ki won maa pariwo ara e kiri.
Bi iroyin Pasito Ajidara se kan sita
Oku Ajidara |
Loju ese
ti won si pari ipade lawon oloye egbe naa loo yoju si ni osibitu Mercy to wa,
ti won si so abo ipade naa fun won, sugbon siyalenu opo won, nigba ti yoo fi di
ale ojo Eti Fraide won ti gbe soro ero ayelujara pe aisan kidirin n yo gbajumo
osere tiata naa lenu, won si nilo owo lati gbe loo si oke okun.
Nigba ti
yoo si fi di aago mefa idaji aaro Sannde, okiki ti tan kaakiri pe Pasito
Ajidara ti ku, opo awon osere ti won gbo ti pejupese si osibitu Mercy ti
okunrin naa dake si, nibe ni won si ti gboku e loo sile igbokusi to wa ni
osibitu Jenera, Ijaye niluu Abeokuta.
Awon omo Ajidara soro
nipa Baba won
Arabinrin Ogunsina
Adedayo Adeshina (nee Adesanya)
Adedayo |
Ile ni mo wa nigba ti won
dake nitori mo wa wo omo mi atawon aburo mi kan nile, lesekese naa ni mo ti wa
ona lati debe ni nnkan bi aago mejila.
Awokose
ti mo ri ko lara won ni pe baba mi kii wo aago alaago sise, o si maa n tele
ilana ofin, temi naa si n ti n tele nitori pe a jo sise nibi kanna an ni.
Adesanya Adedamilare
Oluwaseyi
Oluwadamilare |
Mo
wa legbe beedi won losibitu ki won too jade laye lale ojo naa. Won ti n je
irora yen lati bii ojo merin, ti ale ojo satide yen tun le ju, to je pe aya
gbogbo wa lo ja, sugbon ohun gbogbo ye Olorun Oba. Ni nnkan bi aago mejo abo ale
ni mo gbe egbon mi wa sile, igba ti mo pada debe ni mo rii pe won ti gbe ero
agbemiro (oxygen) si won lara, nibe lokan mi ti n so pe nnkan fee sele, sugbon
a dupe lowo Olorun.
Eko ti mo ri ko lara baba
mi po nitori pe o je alakitiyan eeyan, oro amoran lorisirisi.
EYI LORO TAWON OSERE TIATA SO NIPA PASITO AJIDARA
Inu
ijamba oko ni aisan kidirin ti de si Pasito Ajidara - Tajudeen Edun topo mo si Mogaji tabi
Olori Ebi
Olori Ebi |
Nidi
ise tiata, mo le so pe oga mi ni, mo tun le so pe oga mi ko nitori pe ti a ba
ni ka wo, agbalagba ni, igba tawon n sere ti won, ere oloyinbo ni, tawa naa si
n se ti wa ni Yoruba.
O
pe ko too di pe a pade eyi lo je ki a mo pe omo Yoruba kanna an ni wa, ti a si
nife ara wa gidi latigba naa. Asiwaju rere to see fi yangan ni, nitori pe titi
to fi ku la fi jo rira. Ni gbogbo ona ni mo maa fi maa ranti oga mi, se lori
irin ni ki n so ni tabi lenu ise. Pasito Ajidara ni alaga ile ise eto idajo ti
a ti n sise ko too di pe won feyinti. Nigba ti won si fee feyintin won lo
gbogbo agbara ati ipo won lati rii pe emi ni mo di alaga naa nitori pe idibo ni
won fi gbe mi wole.
Won
o bi aisan kindinrin yi mo Pasito Ajidara, sugbon ni odun 2012 nigba ti won wa lenu ise ni kootu majiisireeti to wa ni
Owode, Sagamu lemi wa nigba naa, owode ni won ti n bo loo sile won ni
ijamba oko to je pe se ni moto yen pare tan, Olorun lo yo won ninu e. Ijamba yi
lo sokunfa kidirin won to n se segesege latigba yen, to si je pe won ko le
se ki won maa lo sile iwosan lati lo sayewo.
Leyin
opolopo osu ni won too bere sii to daadaa, sugbon nigbati aisan to mu won lo yi
maa fi de, se la gba pe asiko Olorun ti to ni. O je alakikanju eeyan to maa n
sa gbogbo agbara e lati se nnkan.
Owo
mi ni Yomi Fash-Lanso ti gba foto to gbe sori ero alatagba - Adeleke Adetutu
topo mo si Seyi Crown, Alukoro fegbe TAMPAN nipinle Ogun.
Seyi Crown |
Ki
a too bere ipade lojoru Wesde ojo keta osu yi, odo won ni mo wa ti won si so pe
mo gbodo wa a jabo fun won lori ipade ti a ba se, won ti e foro ebe ranse pe
awon ko ni le yoju, ki igbakeji soju awon nitori pe won ko tii le so igba ti
won maa fi won sile.
Won
gbiyanju lati dide lati fara han w ape looto lawon ko le dide duro mo, won ni
omo awon lo maa n gbe won ti won ba fee yagbe, tabi to.
Ojo
Wesde naa ni won yo kaadi won pe ki won maa lo sile. Sugbon lojo Friday to tele
ni mo tun pe won pe bawo lara won, nnkan ti won so fun mi ni pe awon fee de
osibitu lati lo sayewo, igba yen lara ti n fu mi pe se kii se pe oro yi fee
yiwo nitori bi won se n soro lojo yen, ohun won ko ja geere.
Won gbe oku Ajidara lo si Motuari |
Ni
nnkan bi aago mefa irole ojo Fraide naa ni aburo mi kan pe mi lati Eko pe won
ni Pasito Ajidara nilo owo lati fi sise abe fun ti aisan kidirin, mo
beere lowo e pe nibo lo ti ri, o so pe Yomi Fash-Lanso lo ko sori ero alatagba,
nigba na ni mo sese war anti pe o ni ki n fi foto ranse laimo pe nnkan to fee
fi se niyen, lesekese ni mo ti pe e pe kilode to fi se bee nitori pe oga o fe
be, o ni oun ti gba ase lowo Mista Lati ati iyawo e.
Gbogbo
igba ti mo wa ni mo n pep e bawo ni ara won,a fi bo se di aago mejila ku ogun
iseju ale Satide tiyawo won pe mi, bi won se pe mi ni ara ti fu mi pe nnkan ti
sele, ni won ba ni Gomina wa ti ku.
Ajidara
je eni to ko iwosi, to si ko ara e nijanu, kii fee kawa omo egbe e maa toro owo
kaakiri.Iwa ajafetoo e lo gbe wo ise tiata, to si maa n gba awa omo egbe
nimoran, ko gbagbo pe ko si nnkan ti ko seese,beeyan ba ti nigbagbo, to si duro
gbingbon.
Mi o le gbagbe owo ounje ti Pasito Ajidara ma
n fun mi - Alaaja Olayinnka Adebanjo topo mo si Say Mama
Olayinka Adebanjo |
Nkan
ti mo si so fenikan laaro yi ni pe boya ironu wipe won gbe sori afefe pe kawon
eeyan dawo fun won lati fi sise abe lo tete mu emi e lo nitori nnkan to korira
ni. O fun wa ni ATM e pe ki a lo gba owo lati fi pari fiimu egbe ti a n ya lowo
A
si jo wa lose to koja nibi ti a ti jo n dapara ni. Gomina mi kii fe ki ebi pa mi. Mi o le gbagbe
igba to maa n fun lowo ounje. Ti m ba pe e pe taya moto mi baje tabi mo nilo
owo, o maa ni ki n wa gba owo ni.
Iyawo kan, omo meta ni Pasito Ajidara bi - Ogbeni Adesegun
Adesinna Emmanuel
Adesina Emmanuel |
Iyawo
kan soso ati omo meta ni Pasito Ajidara ni, odun to koja lo se igbeyawo fun
akobi e. o see se ko je pe ilu Abeokuta ni won maa sin in si, mi o tii le so.
Pasito Ajidara ko tii ju eni odun metale si merinlelogota lo (63-64years).
Olooto Eniyan ni Pasito Ajidara – Oluwagbenga Edun, Alukoro TAMPAN Abeokuta North
Oloogbe Ajidara je olooto eniyan, eni
ti ko kii fi okan bo okan ninu, kii fe toro nkan lowo eeyan, o maa n tiju lati
toro owo loruko egbe. Ko nife si wipe ki a dawo ninu egbe, ki a wa so pe ka
koko yo tawon oloye egbe soto. O nife awa ta n bo leyin, o nife egbe yi dokan,
ko sigba ti Pasito Ajidara kii si ni ofiisi laarin ose nitori ife ti won ni si
egbe.
Alakikanju eniyan to ni afojusun ati
ile pa ni, nitori pe titi ti a fi jo wa ni osibitu ko too di pe o jade laye lo
si n tenumo wipe ki a gbiyanju lati je ki fiimu ti a ya loruko egbe tete jade,
nitori pe oun ni Gomina akoko ti won maa se fiimu loruko egbe jade labe e.
Akobi, Iyawo, Abigbeyin ati omoomo Ajidara |
Bo
tile je pe won ko tii mu ojo ayeye isinku sugbon bi a se n gbo nile oloogbe naa,
sugbon o seese ko je pe ojoru Wesde, ojo ketadinlogun si ojo Abameta Satide,
ogunjo osu yi ni won fee fi si. Iyen tawon molebi atawon igbimo ti won yan ba
jo fimo sokan.
No comments:
Post a Comment