Kani
Friday Michael, eni odun metadinlogbon ti ore e, Badmus Gbadamosi, eni ogun
odun yinbon pa mo pe ibi ti oro naa ma ja si niyen, bo ya ki ba ti tete deyin
leyin e, ko si ti salo jinna rere, nitori ti won so pe se lawon mejeeji jo n gbe inu yara kanna ladugbo
Mamu nijoba ibile Awa-Ijebu, ipinle Ogun.
Badmus |
AWIKONKO
gbo pe ni ojo Abameta Satide to koja yi ni Badmus sare wole ni nnkan bi aago mefa
aabo aaro, ti ko si roo leemeji, to fi yinbo pa Friday nibi to sun si, nitori
awon asiri e ti won loo ti mo nipa awon iwa ibaje (odaran) to n hu laarin ilu.
Won
ni o ti le ni odun meji ti won ti jo n gbe, to si je pe won ni okan lara awon
ogbologbo odaran ni Badmus je, eni ti won lo ti sekupa opo awon eeyan, to si je
pe o tun n jale mo iwa buruku to n hu.
Iro
ibon ti won lawon ara ile naa gbo, lo je ki won sare dide lori beedi ti won sun
ni, ti won si sare jade sita lati mo nnkan to n sele, sugbon won so pe jijade
ti won jade, ni won rii pe inu yara ti Friday ati Badmus n sun ni iro ibon naa
ti dun.
Eyi
lo mu ki opo won maa beere wipe ki lo sele, ki ni won jo n fa, to fi di pe won
n yinbon para won, nitori ti won so pe awon eeyan ko le tete mo pe awon mejeeji
kii se omo iya kanna.
Nigba
ti Badmus rii pe awon eeyan ti ka oun, lo mu ko fe gbiyanju lati fese fe, ko si
na papa bora, sugbon tawon to wa nibe ko je ko ri aaye lati salo, ko too di pe won
ranse sawon olopaa Awa-Ijebu.
Lesekese
ti won ni DPO Awa-Ijebu naa ti gbo, lo ti teko leti pelu awon isangbe e, ti won
si lo lati lo wo nnkan to n sele. Won ni se ni Badmus fee maa bawon olopaa
sagidi ko too di pe o gba lati tele won ni tipatipa.
Bo
tile je pe orisirisi lawon eeyan ti so fawon olopaa nipa awon ti Badmus n hu, amosa,
tesan ni won so pe Badmus ti jewo pe odaran loun, atipe iberu wipe ki Friday ma
baa tu asiri oun sita loun se tete pa, nitori ti won lo o so pe kii se eemeji
lo ti ka oun nibi toun ti lo jale, oun ko si fe ki asiri oun tu loun see woo pe koun ma fina sori orule sun.
O ni nigba ti Friday ka oun lakoko, oun bee pe ko bo oun lasiri, to si je pe o ni koun seleri wipe oun ko ni jale mo, tawon si jo pari e sibe. sugbon nigba to tun ri oun leekeji lokan oun ko ti bale mo, toun si roo pe o see se ki Friday tu asiri oun sita.
O ni nigba ti Friday ka oun lakoko, oun bee pe ko bo oun lasiri, to si je pe o ni koun seleri wipe oun ko ni jale mo, tawon si jo pari e sibe. sugbon nigba to tun ri oun leekeji lokan oun ko ti bale mo, toun si roo pe o see se ki Friday tu asiri oun sita.
Alukoro
ileese olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi so pe awon ti gba ibon to fi
pa Friday lowo e, tawon olopaa Awa-Ijebu to lo lojo naa si ti gbe oku Friday lo
si mosuari nileewosan kan to wa nitosi fun awon ayawo miran.
O
ni Komisana awon, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki awon olopaa digboluja, FSARS tesiwaju
nipa sise iwadi to jinle nipa awon ti Badmus jo n sise, ki won si fi won jofin
nitori to tun so pe oun ko setan lati gba awon odaran laaye nipinle toun n soju
fun.
No comments:
Post a Comment