Bo tile je pe
iyalenu loro Odomobinrin Damilola Adegoke, eni odun mejilelogun to je akeko ile
eko giga gbogbonise tilu Eko, iyen LASPOTECH ti won lo o mu oogun apefon
(sniper) si n je fawon ebi, ore e, paapaa awon araalu lori igbese to gbe lati
gbemi ara e titi di asiko yi.
Damilola Adegoke |
Agbegbe Massa
nipinle Eko nisele naa ti waye lojo Isegun Tusde to koja.
Ninu iwadi ti
AWIKONKO se pelu ohun tawon eeyan n so nipa iku Damilola, ipele kinni lo wa nile
eko giga naa nibi to ti n ko eko owo sise ti a mo si Business Administration.
Ohun tawon eeyan n
so nipe iku e nipe kii soju lasan, yala boya ko lowo aye ninu tabi ko je pe o wa
ninu egbe kan, tawon elegbe e si n so pe asiko to lo laye ti to, ko maa pada
bo, sugbon ko seni to le fi aditu to wa nidi iku e mule.
Lojo Aje Monde to
koja ni Damilola si ko oro ologbon kan sori ero ayelujara Facebook e pe ki won
ma se wo nnkan tawon eeyan n so. See nkan to o mo o se daadaa, maa lepa akosile
ti e ki o si fojusona fun ojo iwaju to dara. Eku ose tuntun (“Never mind what others
say. Do better yourself, beat your own records every day, and aim for a better tomorrow
… Happy new week peeps,”)
Won ni ko fu awon
eeyan lara nipa iku e, bo se je pe se lo n sere pelu awon araale, atipe o ti n
ba iya e tawon eeyan mo si iya ibeji so awon oro kan to mu ifura dani, sugbon
bi iya ibeji ba fee kobi ara sii, se lo maa tun gbe e gba ona miran.
AWIKONKO gbo pe
lakoko ti iya e loo serum e lo gbe oogun apefon naa mu, atipe nigba to n bawon
oniroyin soro laipe yi lo so pe ara ti n fu oun koun too jade nile, sugbon
Damilola lo so foun pe koun tete loo se nnkan toun fee se leekan naa.
O ni ni nnkan bi
aago mesan ale toun maa pada de sile loun ri omo oun Damilola nibi to ti n je
irora lori beedi, koun too ranse pe awon araale lati ran oun lowo, tawon si gbe
e lo si osibitu aladani kan, nibi ti won ti so pe kawon gbe e lo si osibitu
ibomiran nitori pe o koja agbara awon.
O so pe oju ona
lawon wa to ti dake mo awon lowo. Ninu oro e, o so pe “Awa mejeeji nikan la jo
n gbe, ko si sija laarin wa. Ko ba enikeni ja. Laaro ojo yen, buredi ati ata
obe la je. To si so pe oun a fi ata toku je indomie losan. O bo sori beedi, o n
te foonu e, temi naa si fegbe lele.
“Nigba to ya ni
nnkan bi aago kan osan, mo so fun un pe mo fe de odo egbon e lagbegbe First
Gate, o so pe ‘Eyo mi le jare.’ O sese bere ede yen laipe yi to pada de lati
ileewe ni. Emi ati egbon e si ti beere itunmo ede naa lowo e, sugbon ko so nkan
to lodi nipa e.
“Mi o ti e fee jade
lojo naa, oun lo ro mi pe ki n lo sibi ti mo fee lo lai mo pe nnkan to fee se
ti wa ninu e. O ye ko lo ko omo kan nise ladugbo lojo naa, sugbon nigba ti mo
beere lowo e nipa idi ti ko fi lo, se lo jagbe mo mi, ti mo si fi sile.”
“Nigba ti mo maa
pada de ile ni nnkan bi aago mesan ale ojo naa, Mo ba nibi to sun si, mo wa ji,
bi mo se ji yen, mo wa rii pe ipo agbede meji orun ati aye lo wa. Igba ti mo gboorun
enu e, ni mo mo pe oogun apefon lo mu. Lesekese ni mo lo gbe epo pupa ati omi,
ti mo si n roo si lenu ki n too pari fawon araale pe ki won gbami.
“Ko le soro mo. Lesekese
naa ni won ti so pe ka gbee lo si osibitu ti a si gbee lo si eyi to wa nitosi
ile wa. Won so pe o ti ku nigba taa maa debe, a si lo foro naa to awon olopaa
leti. Ko si nnkan ifura lori foonu e nigba ti a ye e wo.” Gege bi iya ibeji to
je iya Damilola se so.
O tesiwaju pe awon
si jo soro ni nnkan bi aago meje koun to dele lojo naa, atipe ipalemo idanwo
saa keji lo n se lowo. O lomo oun maa n sere pupo, o si loyaya sawon eeyan
paapaa ladugbo. O ti e tun so pe Damilola seleri foun pe oun fee ra iyeri-eti
(earrings) foun gege bi ebun ojo ibi oun lojo keta osu kefa to m bo yi.
Okan lara awon ore
Damilola, ti won tun jo w anile eko kanna, Faith Omoh nigba toun naa n soro
lori iku Damilola, o so pe awon si jo dapara lori foonu ni nnkan bii wakati
meji kisele naa too sele. O ni aya oun ja nigba ti mama e pe oun to si salaye pe
Damilola mu oogun apefon.
O lawon ko ri nnkan
ifura nigba tawon ye foonu e wo. O tun so pe won jo gba awon wole sile eko
LASPOTECH lodun to koja ni, idanwo saa keji si ti sunmo etile.
No comments:
Post a Comment