Iyalenu loro awon awako aadota to foju
bale ejo laipe yi si n je fawon to gbo nipa e, nitori bi won se ni ajo to n ye
iwe oko wo, iyen Vehicle Inspection Office, VIO se fi okan-o-jokan esun to nii
se pelu lilodi sofin oko kan won nile ejo.
Gege bi AWIKONKO se gbo, orisirisi
okan-o-jokan esun ni won fi kana won awako aadota naa, eyi ti won so pe aini
iwe oko lo je koko ninu awon esun ti won fi kan won pelu awon esun to tun lodi
si ofin oko ati irinna ko gbeyin ninu esun ti won fi kan won, eyi to mu won
jebi gege bi o ti wa ninu iwe ofin ajo naa lorileede yii, to si mu won foju
wina ijoba.
Nigba to n AWIKONKO wa soro l’Ojobo
Tosde ose to koja, Agbenuso fajo VIO nile kaaro-o-jiire, Ogbeni Taofeek
Abimbola Babalola, eni to tun je olori amuseya so pe bo tile je pe ojoojumo
lawon fi n pariwo, tawon n parowa fawon awako pe ki won rii daju pe won n iwe
oko won n pe ki won too maa gbe oko won soju popona, sugbon eti ikun ni opo won
n ko si.
Taofeek Babalola |
O lowo ti bawon kan to to aadota tawon
si ti gbe won lo sile ejo fun esun otooto to nii se pelu iwe oko, sugbon awon
eeyan naa ti n yipada, won si ti n fowosowopo pelu awon.
Abimbola tun soro lori iroyin kan to
jade laipe yi pe ijoba ipinle Eko labe Gomina Akinwunmi Ambode fi ofin de ajo
VIO fungba die, o so pe bee ko loro ri nitori se ni ijoba n gbero lati gbona
min in yo ti yoo je ona igbalode lati maa fi ye iwe oko wo, eyi ti yoo mu nkan
rorun fawon fawon osise ajo naa, paapaa awon araalu.
No comments:
Post a Comment