B’omo
eni ba dara, o ye ka wi, b’omo eni ba si je idakeji, ko ye ka bo o, eyi lo ni
ibamu pelu ohun tawon eeyan so nipa odomobinrin gbajumo sorosoro ori redio nni,
Adebisi Muibat Oseni, topo mo si Arewa nibi ayeye ojo ibi e to se ni rampe ni gbagede asa, iyen
Cultural Centre, Kuto lojo Aiku Sannde ana.
Muibat Arewa |
Ese
ko gbero, paapaa awon aga ijokoo ko gbawon eeyan ti won wa ibi ayeye ojo ibi
rampe naa nitori ti won so pe Arewa kii se eeyan tawon eeyan ko gbodo ma baa
sajoyo nitori iwa e laarin awon to n ba se.
Bo
tile je pe aago mefa irole ni won l’omobinrin naa pe awon ololufee si lati wa
baa sajoyo ayeye ojo ibi e, sugbon ti won so pe o fee to nkan bi aago meje ki
eto naa too bere ni pereu. Kii se pe Arewa mon-on-mo dawon eeyan duro bi ko se
pe ki eto to la sile fayeye naa le wa si imuse lo n seto e.
Ohun
ti AWIKONKO gbo nipa Muiba Arewa ni pe, eeyan daadaa ni, atipe eni to nife awon
eeyan lo je, ti ki sii se ojusaaju enikeni tabi pe ko maa foju pa awon eeyan
re. Won lodomobinrin naa ni iteriba f’omode, bee naa lo si ni oyaya sawon
agbalagba, paapaa awon to je gege bi oga to ba nidi ise sorosoro.
Okan
lara awon omo egbe sorosoro, FIBAN ipinle Ogun ni Muiba je, eyi lo fa a ti
Alaga ana fegbe naa, Ogbeni Akinyemi Olatoye, topo mo si Alawiye Fediresan ati
Ola-inukan yoju sibi ayeye naa, nitori ohun to daju nipe Alawiye kii deede lo
si pati, paapaa awon pati to ba je pe eni to eni to n se ko ba je eni tawon
eeyan feran.
Nigba
to n soro nipa odomobinrin Muibat, Alawiye so pe omo gidi to se e fokan tan ni
Muiba je, o si je omo to n gbonran sawon agba, paapaa awon oga e nidi ise
sorosoro lenu. O ni ko si ninu awon to n tenu bole so isokuso kaakiri.
Bakanna
ni Arabinrin Adeniji Toyin, tawon eeyan mo si Olori nigba toun naa n soro nipa
Muibat, O ni bo tile je pe Muibat kii se eje e oun, sugbon se lo mu oun gege bi
egbon, to si n gbonran soun lenu. O ni bi won ba n so pe eniyan laso mi, muibat
je okan pataki lara awon to n tele oun.
Nigba
toun naa dupe lowo awon ololufee atawon alaje to wa lori ijokoo, o so pee nu oun
ko gba ope, nitori pe oun ko le so bi inu oun se dun to pelu bawon eeyan se wa
ye oun si. O ni kii se pe oun deedee sagbekale ayeye ojo ibi naa, bi ko se pe
leyin toun woo ore Olorun ninu aye oun, lo je koun roo pe ona wo loun le gba
lati dupe lowo Oba to da oun si, lo je je koun se e ni rampe nitori bi eto oro
aje orileede yi se ri.
O
wa seleri pe oun ko ni rewesi lati maa se boun se n se, iyen awon iwa rere toun
n hu, nitori pe lara awon eko toun ri gba lowo awon obi oun lo fa awon iwa ti
won n ri lara oun.
No comments:
Post a Comment