Adaradenu foro buuruku ranse si Alayo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 9, 2017

Adaradenu foro buuruku ranse si Alayo

Gbajumo olorin Fuji nni to tun je gege bi igbakeji olorin nipinle Ogun, Alaaji Jamiu Adaradenu Jamaika topo tun mo si Oba Seli Fuji ti so pe kawon omo egbe olorin Juju tete fun feere lati fi pe okan lara awon omo aja won to ja sonu pada wa sile.

Adaradenu
Oba Seli Fuji soro yi lakoko to n ba AWIKONKO soro lojo Abameta Satide to koja lo lohun nibi ayeye isinku kan to ti loo forin dawon ololufee laraya nilu Ilaro to tun je ilu abinibi e.

Adaradenu so pe ko si awuyewuye kankan laarin awon olorin Fuji nipinle Ogun, bi ko se pe kawon omo egbe oni Juju tete pe omo aja won to jabo leyin iya e, to n gbo kaakiri, iyen Alayo nitori pe o ti n koja aye e ju bo se ye lo.

O so pe Alayo kere seni to le maa korin bu Asaaju awon olorin Fuji nipinle Ogun, iyen Alaaji Sefiu Alao Adekunle topo mo si Baba Oko, eni to tun je Agbara orin ti ko lelegbe ti ko si ni alatako nitori pe oun leni akoko tawon n wo awokose e gege bi asaaju.

Bi e o ba gbagbe, ko tii ju bii ose meta lo ni won ni ogbeni Ayoola Akinola Michaael forin bu Sefiu Alao nibi to ti lo sere. Kii se akoko re e ti okunrin to pe ara e ni Alayo yii, maa forin bu Sefiu paapaa to ba ti wa laarinn awon ti e, tawon yen si maa n so o sita titi ti Baba Oko yoo fi gbo.


Bo tile je pe won ni opo awon eeyan lo ti pe Alayo lati kilo fun un pe ko sora se, sugbon seni won ni awon oro amoran naa ko wo leti.

Nigba to tun n soro lori awuyewuye to n sele nipa talo da Fuji sile, Adaradenu so pe gege bi aroba tawon ba lenu oga won pe Barrister lo da Fuji sile, sugbon nigba ti Barrister si ti ku, Alaaji Wasiu Ayinde lo kan nitori pe omo Oloogbe Barrister ni Wasiu ayinde je. Bee lo so pe Alaaji Kollington Ayinla je gege bi Baba Oba fun Wasiu Ayinde.

Siwaju si, Adaradenu fokan awon ololufee bale pe awon ise oun kan n bo lona to maa jade sita nitori pea won ti wa ni yara igbohunsile, iyen studio nibi tawon ti n po ise naa papo. O ni bakanna lorin toun ati Sule Alao Malaika jo se naa yoo jade laipe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI