Abimbola Oyeyem |
Leyin osu bii meta
ko too di pe won yan alukoro miran lawon eeyan ti n woo pe nibo wa ni eto aabo
ipinle Ogun n lo, to si je ki won maa sunku sinu pe emi awon ko de mo, bo tile
je pe se lawon odaran da ayeye sile pe aye ti gba awon bayii.
Ko pe sigba naa ni
won so adele naa, Ogbeni Abimbola Oyeyemi di alukoro olopaa to si bere ise ti e
lekunrere. Oro yi pada laarin osu mefa nigba tawon eeyan bere sii kan saara sii
pe ise takun-takun lo n se.
Ni bayii, ko seni
meji tawon araalu n dupe lowo e bi ko se Oyeyemi lo, nitori pe o tun je ki
ajosepo to dan monran wa laarin awon araalu atawon olopaa kaakiri ipinle Ogun,
to je pe ki wahala kan too sele, oun ni won ke si lati ba won yanju e.
Gbogbo Ojoru Wesde
ni Abimbola Oyeyemi maa n wa lori eto kan lori redio ti won pe ni Family FM
laarin aago mesan si mewaa aaro lati so ibi ti ise aabo de duro, tawon eeyan
yoo si so edun okan won fun nipa bawon olopaa kan se n wuwa ti ko bojumu.
Tomode tagba, tonile
talejo lo ni ero ibanisoro alukoro Oyeyemi lowo, to si maa n so fun won pe bi
won ba ri olopaa kan to n gba riba, tabi to n huwa to n doju ti ise olopaa, ki
won fi to oun leti lati fi iya je iru eni bee.
Eyi lo je kawon
araalu mo pe looto lawon eeyan rere si wa laarin awon olopaa lorileede yi,
paapaa nipinle Ogun. Bi e ba fee mo pe looto loro ti a n so, e lo beere wo lowo
awon toro won ti de oluleese olopaa to wa ni Eleweran Abeokuta ri, ki won si so
nnkan toju won ri nipa Ogbeni Abimbola Oyeyemi.
Oyeyemi lo n mu ki
ise rorun fun Komisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu, eni to ti jeje pe
lasiko toun ba si wa nipinle Ogun gege bi Komisana, oun ko ni faaye sile fun
iwa odaran tabi ireje bo ti wu ko kere to. Bee lo si maa n fi kun oro e pe aabo
awon araalu lo je oun logun ju.
No comments:
Post a Comment