Olowu tilu Owu gbawon omo ilu Apomu lamoran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 3, 2017

Olowu tilu Owu gbawon omo ilu Apomu lamoran

Olowu tilu Owu, Oba Olusanya Adegboyega Dosumu ti rawo ebe sawon omo Apomu pe suuru ni a fi n lo ile aye, ki won ma je ki oro oba tabi oye jije so won loruko ti won ko fe, ki won si gba alaafia laaye lati joba.

Olowu
Oba Dosumu soro yii lakoko tawon araalu Apomu ni tile toko lo sabewo si Kabiyesi laafin lojo Eti Fraide to lo lohun nibi ti won ti lo anfaani abewo naa so edun okan won to n je won niya lateyin wa, iyen ti Oba ti won fe.

Olowu so pe o ti le ni ogoji odun toun ti ri ki ese awon omo Apomu pe saafin Olowu, lati wa sepade. O ni awon eeyan naa ti jinna si Owu tii se orirun won, eyi ti ko bojumu. Bo tile je pe Olowu ti koko fesun kan won pe won ko lowo si ise atunse Aafin Olowu ti won sese tunse, to fi di pe won fi n yangan pe aafin won niyii.

Ninu oro Kabiyesi lo ti so pe ileto mejilelogun lo wa ni Owu bo tile je pe meta ni won so pe won damo ninu won, o loun to fa ni pe awon eeyan naa kii yoju sile lasiko to ba ye, eyi to fa ki won maa foju kere ilu Owu.

O so pe atunse ti wa bayii nitori pe awon ti da igbimo kan sile eyi to je pe oun (Kabiyesi) gan an ni olori igbimo naa, ti Oloye Obasanjo to je Aare ana lorile ede yii naa wa lara igbimo naa, bakanna ni awon omo Apomu wa lara won, iyen Oloogbe Olugbemi Ogunbiyi to je Balogun Apomu. Lara awon to tun wa ninu igbimo naa ni Balogun Totoro.

Kabiyesi tesiwaju pe opolopo awon omo Apomu ni won ko te Aafin Olowu ri, ti won o si mo pe omi tuntun ti ru, eja tuntun si ti wonu e bayii, eyi to si ti je ki gbogbo rogbodiyan to n sele laarin awon omo Owu, Apomu, Akin-Ale, Gudugba, Arigbajo di ohun igbagbe.

Olowu ni nigba ti Baba Ajibola si wa gege bi Olowu loun ti ri awon eeyan naa gbeyin. Bee lo so pe oun kofee yoju sawon eeyan naa sugbon awon to ran oun leti pe awon ara Apomu wa lara awon oloye Owu lo Jr koun yoju si won bo tile je pe oun nilo lati sinmi daadaa nitori awon irin ajo kan toun n lo lenu ojo meta yi.

Saaju akoko yi ni Oloye Olufemi Osanyinjobi to je Olori igbimo Apomu Owu ti so pataki ohun to gbe won wa. Nigba to n pa itan isedale ilu Apomu, o so pe gbogbo awon ilu kerejekereje to de leyin Apomu bii Akin-Ale, Papa, Ejio ni won ti ni Oba, sugbon ohun ko mo idi ti Apomu ko fi tii ni Oba titi di asiko yii.

O wa rawo ebe si Olowu pe ki o bawon fi ase ati onte si Oloye Olalekan Olasode Olaonipekun to je Baale Apomu gege bi Oba Apomu, ki won si le tete bere igbese naa lati odo ijoba ipinle Ogun lati gba iwe eri.

Oloye Osanyinjobi so pe bo tile je pe o ti n pe ti Kabiyesi Olowu ti n fe kawon ara Apomu yoju saafin, sugbon asiko ko tii to nigba naa nitori ede aiyede to n sele laarin won. O wa ni asiko naa ti to bayii, nitori pe nnkan to n di won lowo nipe won ko tii fenuko, sugbon ni bayii, awon ti wa ni irepo.

Leyin naa ni Kabiyesi so pe inu oun dun pe awon eeyan naa mo pe kii se pe ko si oba ni Apomu, nitori pe Akin-Ale ati Ejio, Apomu ni won ti jade, sugbon ko sohun to buru ti oba ba pe meta, merin laarin ilu nitori pea won Egba naa ni Oba meta, iyen Alake, Osile ati Agura, amosa, suuru lo se pataki. O ni laipe, ohun ti ko to si n bo wa seku.

Oba Dosumu wa gba awon eeyan Apomu lamoran pe ki won lo ni osuka ilosiwaju tii se ife, irepo ati ifowosowopo. O ni eru ko see ru lai lo osuka atipe osuka ilosiwaju ni ife ati irepo.

Kabiyesi nigba to n kadi oro e so pe ki won lo forikori, fikunlukun lati fa eeyan kan kale lati ropo Oloogbe Ogunbiyi to je Balogun Apomu to file sasobora. O ni kii se pe ki won mu eeyan kan lasan wa bi ko se pe ki won wa eni to le se ju Oloogbe naa lo, nitori pe Oloogbe naa ni iwa tutu ati iteriba, to si n fe ki alaafia joba laarin awon oloye paapaa laarin ilu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI