Hassan mu igbo tan, Lo ba be sodo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 3, 2017

Hassan mu igbo tan, Lo ba be sodo

Bo tile je pe ohun tawon kan n so ni pe oro naa lowo aye ninu, sugbon titi di asiko ti a fi n ko iroyin yi lawon ebi odomokunrin kan, Hassan Fadipe, eni odun mokandilogun ti won ni igbo lo mu ko too be sodo, to si gbabe ku si n je kayeefi paapaa fawon araadugbo naa.

Hassan to be sodo
Gege bi AWIKONKO se gbo, adugbo kan ti won n pe ni Onireke, Alowonle ni Mango Adigbe nisele aburu naa ti waye lojo Aiku Sannde to koja, nigba ti won so pe aso ni Hassan so pe oun fee lo fo lodo ni nnkan bi aago mejila osan ojo naa.

Won ni bo se de be, lo ti ko aso to fee fo naa sile to si gba odo iya to n ta igbo fun won nitosi odo naa lo, to si ra igbo meji, lo ba muu yo keri. Leyin ti won lo mu igbo yi tan ni nnkan yiwo fun un, to si bere sii se wonranwonran, gege bi a se gbo.

Won ni lara awon ore e ti won jo lo mu igbo naa fi n se yeye pe meloo lo mu to n se bii alaaganna lai mo pe oro e ti kuro loju lasan ti won fi n wo o. Ohun ti a gbo nipe Hassan ko sese maa mu igbo. Atipe won ni ko tii pe odun meta ti baba e ku koun naa to je Olorun nipe.

AWIKONKO tun gbo pe nigba ti won rii pe oro naa ti yiwo fun pelu bo se n sare kiri to si n se awon nnkan afagbara se, lo je ki won maa le lati mu, sugbon bi won lo se sare de odo lo yiju pada to si so pe ki won pada leyin oun, lo ba be sinu odo to ti fee foso.

Bo tile je pe won ni ko sese maa we lodo naa, sugbon ohun ti won ro nipe o fee we ni, atipe ko ni pee jade, eyi lo mu ki won maa wo niran lati pidon to fee pa. Sadede ni won ko rii mo, ti won lo ti ri sinu omi naa, to si ti gbe e lo.

Lara awon ore e tawon naa maa n we lodo ni won be sinu odo naa lati wa, sugbon won ko ri. Eyi lo mu won lo pe awon agbalagba ti won mo bi won se n we, lati wa ran won lowo, sugbon tile ojo naa fi su ni won ko rii.

Gege bi ohun ti won maa n so pe “Abiyamo kii gboku omo e ko ma taji were”, gbara ti won niroyin naa ti te iya e lowo nibi to wa lo ti sare dide to si pariwo ‘e gba mi, e ra mi kale, tani mo se’, bee ni won lo sare de odo naa pelu iro lasan nidi.

Eeso ni won ni obinrin naa n ta, to si fi n bo awon omo e latigba toko e ti ku. Awon araadugbo ni won ni won n rawo ebe si iya e pe ko ni suuru, won si maa ri, sugbon oun ti won lo n so nipe se ti won ba ri, se o fee ji pada ni.

Lara awon to bakoroyin wa soro lojo Aje Monde so pe ise awon to n se gilaasi ile, iyen aluminionu lo n ko latigba to ti jade ile iwe girama lodun 2015. Won ni Hassan kii se omo buruku tele, sugbon awon ore to ba pade nibi to ti n kose ni won ko bi won se n mu igbo.

Ni nnkan bi aago merin irole ojo keji, iyen ojo Aje Monde ni won sese ri ti omi naa ti gbe e pada wa sita, ko too di pe won lo foro naa to awon eeyan e leti. Lesekese ni won ni won ti seto bi won se sin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI