Alayo |
Won ni Alayo so pe ti agba olorin
naa ba n se e fawon kan, ko ma se e de odo toun nitori pe oun ti di igi eleera
ti ko see gbe dani sere.
Ibinu ni won ni okunrin naa fi korin
bu Sefiu Alao lojo naa, sugbon won lawon to wa nibe lojo naa ni won ni ko
panumo, ko ma soro seni to juu lo.
Bi won se ni Alayo gboro naa lo tun
so pe, bi eni to ju oun lo ko ba fe arifin lodo oun, se ni ki eni naa duro nipo
toun ba gbe e si.
Bee lo tun ni ki Sefiu Alao woju o,
nitori pe onikaluku lo ni nnkan to gbojule.
AWIKONKO gbo pe, bi okan lara
awon to sunmo Alayo se gbo oro yi, lo ti pe e lori foonu lojo keji pe ki lo ri
lobe to fi wa iru sowo, to fi je pe Sefiu Alao lo tun n korin bu.
Sefiu Alao |
Nje kini Alayo so pe Sefiu Alao se
foun, o ni lojo to n se ojo ibi loun pe lati ki ku ayeye ojo ibi ni aaro di
irole ojo naa, sugbon ko gbe foonu e, ti ko si pe pada lati so pe ki lo sele
titi di asiko naa.
Alayo tesiwaju pe kii se igba akoko
ti Sefiu Alao maa hu iru iwa bayi soun niyii, o lo o ti n se tipe, sugbon oun
ko le muu mora mo nigba ti ko seni toun fee fejo e sun.
Alayo tun so pe oun mo pe toun ba
gbe e gba ona koun forin bu, awon to sunmo Sefiu nibi toun ti lo korin yoo mu
iroyin naa te lowo, ti yoo si pe oun pada lati bebe.
Ohun tawon to n gbo nipa isele naa
ni won n so pe igberaga okunrin ti won pe ni Alayo naa ti poju, atipe ko seni
ti ko le soro si.
Titi di bi a ti n koroyin yi, bo
tile je pe Sefiu Alao ti gbo nipa isele naa, sugbon ko tii fesi sii. Oun tawon
to sunmo Sefiu so nipe, ete ni Alayo n wa.
No comments:
Post a Comment