Won
ni Olorun lo yo iyawo e naa
Bi eeyan ba je ori ahun, to ba de ibi
isele buruku yii lojoru Wesde ose to koja nibi ti okan lara awon tirela Dangote
ti gba baba agbalagba ti won lojo ori e ti le ni ogota odun to si ku lesekese,
yoo sukun lojo naa.
Layipo Papalanto si Ilaro ni won so pe
eni to wa tirela naa ti n bo pelu ere asapajude ti won lo n sa, ko too di pe
igba ti yoo fi so pe koun gboju soke, aso ko ba omoye mo, o ti kan olokada naa
lara.
Pati ni won so pe baba naa ati iyawo e
ti n bo ko too di wipe won sagbako isele buruku naa, bo tile je pe egbe ona ni
won so pe tirela naa ti loo ba won.
AWIKONKO gbo pe loju ese toro naa ti
sele ni awako naa ti poora, ko seni to le so pe bo se rin in re, o ti na papa
bora.
Leyin nnkan bi wakati kan aabo ni won
so pe awon olopaa too gbe oku baba naa lo si mosuari jenera osibitu to wa ni
Ifo.
Bo tile je pe iyawo baba agba naa toun
naa ti le ni aadota odun ti won jo wa lori okada ko farapa, sugbon ekun to n
sun ni pe nibo loun fee gba, eru eeyan meji ti di toun.
Titi di bi a ti n ko iroyin yi jo lawon
olopaa si n wa awako naa bo tile je pe won ti wa tirela naa lo si ago won lati
tesiwaju lori ise iwadi won, gege bi a se gbo.
No comments:
Post a Comment