Osupa ati Pasuma |
Lojo Aiku Sande ose to koja ni gbajumo Fancy Aye Alamu pe
awon osere onifuji meji nni lati wa lara awon ti yoo sere nibi ayeye ifilole
kaseeti to pe akole e ni “Na God”.
Bi ayeye naa se n lo lowo ni Saheed Osupa ti koko debe, ko
si pe lo bo si ori itage, to korin. IROYIN OWURO gbo pe bi onifuji ohun se n
korin lowo niroyin kan sii pe Wasiu Alabi Pasuma naa ti de, to si fee wo
gbongan ibi ayeye naa.
Ariwo yi ni won ni Saheed Osupa gbo to fi korin naa
paapaapaa, koda, gbogbo awon to fee ki ni ko duro ki won, to si fee ssare tete
bo sita, sugbon bo se bo sita si enu-ona abajade lo se konge Pasuma.
IROYIN OWURO tun gbo pe, iyalenu lo je pe se ni Osupa koko
gboju bi eni ti ko rii, to si fee gba egbe e koja, sugbon bi Pasuma se rii lo
fi ejika e gba legbe, ko too dipe won di mo ara won.
Won o lo ju iseju kan ti Osupa fi kuro nibe lo sibi to tun
ti fee sere ninu ogba redio naa sugbon awon to wa nibe ti won ri nnkan to sele
ni won so pe se ni Osupa mo on-mo sa fun Pasuma, atipe won ni kani o mo pe
Pasuma tete maa de sibi ayeye naa, boya ko ba di bi owo irole koun too yoju.
Lara awon osere to tun sere nibi ayeye naa ni Abass Akande
Obesere, iyen Omorapala. Bakanna ni Sunny Ade, Kollington Ayinla ko gbeyin nibi
ayeye naa.
No comments:
Post a Comment