Republic
of Benin ni won ta si
Afi bi eni
to je furo adie loro Musa atawon ore e meta towo palaba won segi lose to koja
ri, nigba ti won se bere sii ka gbogbo oran ti won ti da seyin.
Musa atawon ore e |
Gege bi
atejade ti Alukoro olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi fi sita lojo Aje Monde
ose to koja, agbegbe kan ni Seme ti won farapamo si lasiri won ti tu nigba
tawon olopaa FSARS lo koju ija si won.
AWIKONKO
gbo pe lojo ketadinlogbon osu kinni odun yi ni Hassan Musa, eni odun
marundinlogbon; Segun Idike, eni odun mokandinlogun; Adewale Rasak, eni odun
metadinlogbon; ati Keneth Ohimai ti won loun lo dagba ju laarin won, ti won so
pe eni odun mejidinlogoji ni lo dena gba moto Giwa ileeko giga Fasiti Crawford
to wa ni Igbesa, ipinle Ogun, Ojogbon Rotimi Ajayi.
Jiipu
Toyota Highlander won lawon odaran naa ja gba lowo Ajayi pelu ibon lowo loju
ona Atan si Igbesa laaro kutu ojo naa, nigba ti won so pe, okunrin naa n lo si
ibise e lojo naa ni.
Loju ese
toro naa ti sele ni won lokunrin naa ti lo fi to awon olopaa leti, tawon yen si
bere sii sise iwadi won.
Lojo ti
isu maa dile leyin oloko won, fun bii wakati kan aabo gbako lawon odaran naa
atawon olopaa fi koju ibon sira won, bi eni pe won sere tiata loro ri lojo naa,
to si di bolo o yago laarin won.
AWIKONKO
gbo pe okan lara won ti ibon ba legbe, iyen Joseph Housus ri aaye lati na papa
bora pelu ota ibon lara e. Inu ilu kan ti won pe ni Ajase ni Republic of Benin
nibi to ti n gba itoju ni won ti rii mu, sugbon gbogbo akitiyan lati mu wa si
Naijiria lo ja si pabo.
Ninu oro
ti Musa so lo ti jewo pe Republic of Benin lawon ta moto naa si, atipe kii se
akoko tawon maa se iru nnkan bayii niyii.
Abimbola
so pe, ibon merin ati ota ibon to to ogbon ni won ri gba lowo won, bo tile je
pea won si n gbe igbese lati bawon agbofinro nibe soro lati gba moto naa pada
fun eni to ni.
Komisana
olopaa, Ahmed Iliyasu ti wa gbawon olopaa FSARS niyanju lati tubo tepa mo ise
won, ki won le rii daju pe won pa iwa odaran run patapata nipinle Ogun.
Bakanna lo
wa ro awon araalu lati tubo maa fawon olopaa ni iroyin nipa ibi ti won ba ti
kofiri awon odaran, nitori alaafia won lo je olopaa logun julo.
No comments:
Post a Comment