Oro buruku toun terin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 23, 2017

Oro buruku toun terin


Sulaiman ati Sakiru foju bale ejo nitori erepa

"E dakun e foju aanu wo wa. E dari ji wa, ise esu ni" lorin ebe ti Sulaiman Elewure ati ore e Sakiru Sobowale n ko ni Kootu Majisireeti to wa ni Isabo Abeokuta lOjoru Wesde ose to koja nigba ti won ka esun merin otooto le won lori, lara eyi ti won so pe won ju okuta lu ilekun ogba olopaa.

Alukoro Abimbola Oyeyemi
Bo tile je pe Adajo to da ejo lojo naa, iyen Arabinrin Oriyomi Sofowora ti so pe oun fi aaye sile pe ki won gba beeli won ni egberun lona ogorun naira pelu oniduro meji to si sun igbejo lori esun naa siwaju di oni ogunjo, sugbon ko seni to gbo oro naa ti ko nii mo pe ohun gbogbo lo ni ofin ti e.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ere ipa ni won so pe Sulaiman ati Sakiru n se, titi to fi di pe won n ju okuta lu ara won, leyi ti won ko lero pe o le gbe won dele ejo lati kawo ponyin rojo niwaju adajo.

Bi won se n ju okuta lojo naa lawon toro naa soju ti n kilo fun won pe ki won so ewe agbeje mowo koro naa ma si da wahala sile laarin awon mejeeji, sugbon se ni won n so pe ko si nnkan to fee sele.

Okuta yi ni won so pe won seese ju to si fo gilaasi soobu enikan to n taja, ti won pe oruko e ni Azizat Adeboye, tiyen naa si so pe oun ko nii gba, ayafi koun gba owo oun tabi ki won ra gilaasi miran pada foun.

Iyen nikan ko, won lawon eeyan naa tun ju okuta lu awon to n koja lo, paapaa awon olokada atawon to joko jeje won niwaju ita ile won. Agbegbe Sabo ni won ti hu iwa naa.

Won lori to ba maa je iko, bo ba we igba lawaani, yoo si, eyi lo mu ki esu ti won loo fa duro ti won gboingboin lojo naa, ti won si tun ju okuta lu geeti ogba olopaa to wa lagbegbe naa.

Agbejoro awon olopaa, Ogbeni Sunday Eigbejiale nigba toun n soro niwaju adajo so pe awon nikan ko ni won huwa yii lojo naa, o lawon toku salo nigba tawon fi maa lo ko won, sugbon Sulaiman ati Sakiru lowo awon te.

O ni yato si wipe won fi okuta ba soobu Azizat je, won tun se awon nnkan to le da wahala sile laarin ilu, leyi ti ko ni fi aaye sile fun alaafia.

Eigbejiale so pe ese ti won se naa tako ofin ijoba ipinle Ogun todun 2006, leyi ti won si gbodo fi won jofin kawon araalu baa le fi won kekoo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI