Omi tuntun ti ru ni Kooko Ebiye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 1, 2017

Omi tuntun ti ru ni Kooko Ebiye

Won ti l'Oba tuntun leyin odun mesan

Ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun ti yan Oba tuntun fun ilu Kooko Ebiye nijoba ibile Ado-Odo Ota lose to koja. Oba Joel Fashina, Ilufemiloye kinni ni o gba opa ase leyin ti Oba Simeon Olatunji Fasina waja lati osu kewaa odun 2008.

Babajide Ojuko
Oloye Babajide Ojuko, to je komisanna foro oye jije nipinle Ogun nigba to n gbe opa ase le Oba tuntun naa lowo so pe, fifi Oba Joel je ko seyin lati pa ina wahala to ti wa nile laarin awon loye nipa eni ti won fee fa kale gege bi Oba tun.

O so pe latigba ti wahala naa ti bere ni ijoba ipinle Ogun ti gbe igbimo kan dide lati sewadi eni ti ipo naa to si, ti ko si ni da wahala sile lojo iwaju. O ni leyin iwadi igbimo naa ni won rii pe Oba Joel ni ipo naa to si, eyi to si je pe latigba naa ni ijoba ti n gbe igbese lori bi ayeye ifoba je naa yoo se waye.


Oba Joel nigba to n soro so pe oun dupe lowo ijoba ipinle fun ise takuntakun ti won se, ati igbese se ti won gbe lati rii pe won pana wahala naa. O wa ro awon araalu lati fowosopo pelu oun lati mu idagbasoke ba ilu naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI