Bi ayeye naa ti se n sun mo etile ni
igbese ara-oto tun n dide lati le mu ki ayeye Festac 77 ogoji iru e todun yi
larinrin, ko si ni gbongbon ninu, eyi ti yoo si ko ipa to po ninu igbesi aye
awon omo ile Afrika.
Lara eto ti ajo to fee sagbateru ayeye
naa ti la sile ni ti bi Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja keji se maa
gbe ade le Aare teleri lorile ede yi, eni to tun je Balogun Owu, Oloye Olusegun
Obasanjo gege bi Oba Ruby, iyen King Ruby ati asiwaju asa nile Afrika.
Gege bi AWIKONKO se gbo, idi ti won fi
fee fi ebun ade naa ta Obasanjo lore ko seyin ti ipa ti won lo n ko nipa
idagbasoke asa ati ise nile nile adulawo, iyen Afrika.
Pataki idi to tun fi fee gbade naa ni
bo se je pe oun gan an lo fase si lati bere ayeye naa lodun 1977 lasiko to wa
nipo gege bi Aare ologun, bo tile je pe o ti to nnkan bi odun marun ti won ti n
ja fun isese naa.
Osu karun odun yi ni Balogun Owu
yoo gbade naa nilu Abuja, lara eto ti won si ti la kale fun ayeye naa, eyi ti
yoo bere lojo kini osu kerin, leyi ti won fi fee saami ayeye ogoji odun ti won
ti n sayeye naa lorile ede Naijiria.
Alakoso ayeye naa, Dokita Anikwe nigba
to n soro lojo Isegun Tusde to koja so pe ajo Centre for Black and African Arts
and Civilization ti pari ise lori bi eto igbade naa gege bi Oba Ruby yoo se
waye.
Anikwe so pe iru ayeye bayii ko se e fi
we ayeye eyi to wu ko ti maa waye nigba to je pe gbigbe asa ati ise ile Afrika
laruge lo si wa fun. O ni nigba ti Obasanjo ti ri Pataki oun ti ayeye yi yoo se
forile ede Naijiria lo ti je ko tete ranse sawon eeyan lati fowosowopo pelu e,
ko si je eyi ti gbogbo agbaye maa sagbateru e ko too di pe won bere e lojo
keedogun osu kinni odun 1977 si ojo kejila osu keji odun naa.
Bi e o ba gbagbe pe lodun to koja ni
Oloye Olusegun Obasanjo lo se abewo kade o pe lori fun Ooni Ile Ife nibi to ti
fi iwa omoluabi han, ti baba agba naa si dobale fun ori ade, iyen Oonirisa, eyi
to ya gbogbo aye lenu pe iru iwa omoluabi bayi ko wopo, paapaa laarin awon
oloselu, eyi lo si fa to fi je pe Ooni lo fee gbe ade naa le Ebora Owu lori.
Gege bi eto ti won tun ti la kale,
ipinle mewaa otooto ni won ti fee se ayeye naa, eyi ti ilu Abuja tii se olu-ilu
orile ede yii ko ni gbeyin nibe. Lara awon ipinle naa ni Akwa-Ibom, Enugu,
Kaduna, Katsina, Ogun atawon min in.
No comments:
Post a Comment