Baba
agba kan, Ogbeni Ayoola Rasaki Kassim, eni odun mejilelogorin, to je agba
onisowo ti rawo ebe si ajo to n ri soro sise owo ilu mokumoku, iyen ajo EFCC,
oga olopaa lorile ede yii, Ibrahim Idris ati gomina ipinle Eko, Akinwunmi
Ambode lati gba oun lowo loya to lu oun ni jibiti lori oro ile.
Gege
bi AWIKONKO se gbo, ninu leta alabala meji ti baba naa ko si alaga ajo EFCC
lojo kejidinlogbon osu to koja lo ti fesun kan agbejoro agba kan lorile ede yi,
Ogbeni Olalekan Yusuf pe o gba ile oun to wa ni nomba 14, adugbo Oyetola nitosi
adugbo Ajanaku, Opebi, Ikeja nipinle Eko lona aito
O ni
lojuna pe ijoba apapo n gbiyanju lati ri owo iwabaje bole lorile ede yii ni
gbogbo eka, ki ajo EFCC, awon olopaa ati ijoba ipinle Eko dakun tete ba oun gba
dukia oun pada lowo onijibiti agbejoro naa.
Ninu
iwe ifesunkan naa, eyi to te AWIKONKO lowo lojo Aje Monde ose to koja lo ti so
pe ojo kejo, osu kerin odun 1999 loun ti ra ile naa lowo Arabinrin kan,
Ibironke Samuel to je omo agba oloselu nni, Oloogbe S. O. Shonibare ti egbe
oselu Action Group tele ni milionu merin naira. O so pe eemeji otooto loun san
owo ile naa.
O ni
ojo kewaa osu keta loun koko san milionu meji naira, toun si san milionu meji
naira toku lojo kejo osu kerin odun 1999. O so pe gbogbo igbese lati gba ile yi
nigba naa lo ja si pabo nigba to so pe agbejoro naa, iyen Yusuf ti la fandesan
sori e.
Baba
agbalagba naa nigba to n soro pelu omije loju so pe Adajo ile ejo giga kan nilu
Eko lo fi ofin gba ile naa fun Ogbeni Yusuf pelu adehun to wa laarin won eyi ti
won se ayederu eda iwe ile naa, ti won si tun se ayederu itowobowe eni to ta
ile naa foun, iyen Arabinrin Ibironke Samuel.
Baba
naa, iyen Ayoola so siwaju ninu leta to fi tii nidi eyi ti oga olopaa, Ogbeni
Udenze ti Forensic and Crime Data Department fowo si lo ti so pe ayederu onte
to je ti Arabinrin Samuel lo wa ninu awon iwe eri naa.
Bakanna
la tun gbo pe ko too di pe Yusuf gba ile naa, lo ti je agbejoro feni toun ati
Arabinrin Samuel jo fa oro ile naa ni kootu ko too padanu e sowo obinrin naa,
sugbon bi o se wa di pe oun lo tun gba ile naa ni ko ye enikan.
Gbogbo
igbese ati akitiyan AWIKONKO lati ba Ogbeni Yusuf soro lo ja si pabo lori bi
awon to n gbe ninu ile ti won n so yii se so pe awon ko le juwe ibi tokunrin
naa n gbe. Sugbon baba agbalagba naa so pe bo se n se niyen atipe o ti ledi apo
po pelu awon to gba sile.
No comments:
Post a Comment