Nitori Ayeye Odun Lisabi: Alake gboriyin fun ileese Globacom - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 1, 2017

Nitori Ayeye Odun Lisabi: Alake gboriyin fun ileese Globacom

Alake tile Egba
Loni in tii se ojo Aje Monde ni ayeye odun Lisabi eyi ti won maa n se lodoodun ti ikokanlelogbon yoo bere. Gege bi Alake tile Egba Oba Michael Adedotun Aremu Gbadebo se so lakoko to n bawon oniroyin soro lose to koja, o ni akori todun yi ni “Igbelaruge Ise Ogbin lona ti yoo mu idagbasoke ba ile Egba ati orileede Naijiria”.

 Bee lo lo akoko naa lati fi gboriyin fun ileese ibanisoro Globacom fun akitiyan won lori igbelaruge asa ati ise. O ni nitori idi e lawon se gba ki ileese naa maa sagbateru ayeye naa, eyi ti won ti n se lati nnkan bii odun meloo kan seyin.

O salaye pe kii se ileese naa nikan lo ti n se agbateru eto naa tele, sugbon nitori imoriri won nipa asa ati ise, eyi ti won n se kaakiri orileede yii lo je kawon naa fun won laaye lati maa sonigbowo, eyi to si ti mu opo idagbasoke ba ayeye naa.

Siwaju akoko yii, Alake so pee de Yoruba se pataki lati maa se agbelaruge e ninu asa ibile. O so pe “eni ti ko ba gbe ede e laruge, o so apo iya ko ni”, nitori naa lo se je awon ko setan lati gbe ede miran laruge bikose ede tiwantiwa.

Nipa akori todun yii, Oba Gbadebo so pe kii se pe ise agbe nikan lo le yo orileede yii kuro ninu eto oro aje to forisanpon bikosepe bi ebi ba kuro ninu ise, ise ti buse nitori naa lawon se fee se iranwo fawon agbe lodun yii ki ounje le tubo posi.

Nigba toun naa n soro, asoju ileese Globacom, Ogbeni Yomi Ogunbanwo so pe awon ko kabamo pe awon n sagbateru ayeye odun Lisabi atipe ayeye naa yato gedengbe sawon ayeye isembaye toku nile adulawo. O wa ni awon ko tii setan lati dawo ajosepo won duro bikosepe kawon tun tesiwaju lati maa mu idagbasoke ba ayeye odun Lisabi.


Lara awon to wa nibi ayeye naa Oloye Raji Rasidi to je alaga ayeye naa, Oloye Arabinrin Yemi Olanrewaju, Ogbeni Dare Folarin, Oloye Fatai Abodunrin, atawon oloye Egba min in. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI