Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yi
lawon alaga ijoba ibile ati idagbasoke, iyen LCDA metadinlogoji ti ijoba ipinle
Ogun fi kun ijoba ibile ogun to wa nipinle naa si n wotun wosi lori bi won yoo
se ni ofiisi ti won.
Gomina Amosun |
Bi e o ba gbagbe, osu yi gan lo pe osu
marun leyin ti idibo ijoba ibile ti waye nipinle Ogun, sugbon latigba naa lawon
ti won ni won dibo yan naa si n rin kaakiri lati wa ibi ti won yoo maa lo gege
bi ofiisi ti won.
Gege bi okan lara awon to wa nipo oselu
taa fi oruko bo lasiri to gbe oro naa si AWIKONKO leti se so, o ni bo tile je
pe ona eru ni won fi gbe awon alaga atawon kanselo naa wole, sibe won si n lobi
kaakiri lati wa ile tabi yara ti won yoo maa lo gege bi ofiisi.
Ninu osu kewaa odun to koja ni idibo
ijoba ibile ati idagbasoke waye nipinle Ogun, to si je pe egbe oselu All
Progressive Congress, APC nikan lo yege laarin awon egbe oselu bii marun to
kopa nibi eto idibo naa.
Sugbon ninu osu kokanla ni Komisana
foro oye jije ati idagbasoke agbegbe nipinle Ogun, iyen Oloye Babajide Ojuko se
ibura fawon eeyan naa to si seleri owo atawon eto to to si won fun won.
Leyin naa ni Gomina ipinle Ogun, Asofin
Agba Ibikunle Amosun ba won se ipade toun naa si se ileri owo ile, aso ati
dukia to je gege awon ohun ti won leto si fun won.
O seni laanu pe latigba ti Ojuko ti
bura fun won, to si seleri lorisirisi, ti Gomina Amosun naa se ileri ti e titi
di asiko yi, ko tii seni to le fowo soya pe oun ti ri eto tijoba ipinle Ogun
seleri e fun won gba, bo tile je pe won ri owo osu gba diedie.
Lara awon alaga ijoba ibile ati
idagbasoke agbegbe tuntun ti won sese yan yi ti bere sii fehonu han labele si
gomina Amosun bo tile je pe ko seni to to be ninu won lati gbin nigba to je pe
ohun to foju han kedere fawon araalu ni pe ona eru ni won fi yan won.
Gege bi iroyin to tun te AWIKONKO leti
se fi han fun wa, ni pe opo awon akanse ise to to si awon alaga ijoba ibile ni
won ko tii bere. Bee, lara awon yara kan ti won ya sile fun ijoba ibile
Abeokuta North ninu ogba ile eko Owu African Church Central to wa ni agbegbe
Ita-Iyalode nilu Abeokuta ni won si tipa ti ko si ni lilo fawon to to si.
Bakanna ni ijoba ibile idagbasoke Remo
Central to wa ni Iperu lona Ilishan-Remo ni won ti pa, ti ko si ri eni lo ohun.
Bee naa ni won ko tii pari ofiisi ijoba ibile idagbasoke to wa ninu ogba ijoba
ibile Abeokuta South tele lagbegbe Ibara titi di bi a ti n koroyin yi.
Alaga ijoba ibile ati idagbasoke
Abeokuta South/South nikan ni ofiisi e si pari ninu yara ikawe kan to wa ninu
ogba ile-eko alakobere to wa ni Idi-Aba, Abeokuta.
Ohun ti a tun ri gbo ni pe ogba ijoba
ibile ati idagbasoke to wa ni Ijebu Ode South lagbegbe Oke-Aje ati eyi to wa ni
Ketu lagbegbe Tata, iyen ni ijoba ibile yewa atijo ni ko dun un wo loju lori bi
won se so pe awon ibe yen ti baje, to si n fe abojuto.
Agbalo-agbabo, kaka ki alaga ijoba
idagbasoke Abeokuta North, Ogbeni Taofeek Olabode bebe fun ofiisi e, nise lo so
ile e to wa ni Lafenwa di ofiisi nibi to ti n dawon eeyan lohun. Bakanna loro
ri pelu alaga idagbasoke Sango/Ijoko, iyen Ogbeni Fatai Lawal, toun naa so ile
e di ofiisi.
No comments:
Post a Comment