Leyin odun meje; Won foba tuntun je ni Erunwon - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 14, 2017

Leyin odun meje; Won foba tuntun je ni Erunwon



Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ti gbe opa ase fun Oba Adebayo Johnson Okubena, ti idile Dedenigbo gege bi Oba Erunwon tuntun nijoba ibile Ijebu North East.

Gomina Amosun
AWIKONKO gbo pe lati nnkan bi odun meje seyin ti Oba ana ti waja, iyen Oba A.O Awofeso ti idile Lemoye Lesu ti papoda lawon oloye atawon araalu ti n bebe fun Oba miran ti yoo ropo e.

Gbagede ileeko alakobere Epiphany to wa lagbegbe naa ni ayeye naa ti waye lose to lo loun nigba tawon eeyan jankan-jankan bii Awujale tile Ijebu, Oba Sikirulai Adetona, Alaga ijoba ibile naa, Onarebu Sunday Onafuye ati Olori idagbasoke Yemoji, Onarebu Dapo Adebajo ko gbeyin nibe.

Nigba to n sapejuwe Oba naa, Amosun ti Komisana foro ijoba ibile ati oye jije soju e nibi eto naa so pe oun ri Oba naa gege bi olufowopo idagbasoke loje ninu isejoba ti won pe ni Mission to Rebuild.

O wa ro Oba naa lati gbawon eeyan niyanju nipa sisan owo ori won deede, nitori ko sohun to le tubo mu idagbsoke ba ilu bi ko se sisan owo ori lasiko lo.

Awujale tile Ijebu dupe gidi lowo Gomina Amosun fun ona to n gba lati da si oro oloba ati oloye de lo nipinle naa. Bakanna ni Kabiyesi tuntun naa dupe lowo ijoba ipinle Ogun, o wa se ileri pe oun yoo lo ipo oun lati mu ki alaafia tubo joba nilu, atipe oun yoo faaye sile fawon to ba ni amoran to le mu idagbasoke ati isokan ba ipinle Ogun, paapaa ilu Erunwon.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI