AWIKONKO: Nje a le mo yin, pelu ipo ti e di mu?
BAALE: Oruko
temi ni Dauda Adedeji Adegboyega Ajala. Emi ni Baale Ilu Idi-Ori nijoba ibile
Abeokuta North. Odun 2010 ni mo je Baale.
Baale Idi-Ori, Oloye Adegboyega |
AWIKONKO: Nje e le so die fun wa nipa itan isedale
Idi-Ori?
BAALE:
Itedo yi je ti Owu. Ni odun 1834, nigba ti awon baba nla wa kuro ni Orile, ti
won de ilu Egba, Idi-Ori ni ileto akoko ti won koko de lati sise oko. Awon meji
ni won koko wa, ise ode lo gbe won wa. Ti won ba ti fee sise ode tabi ise oko,
won a bo aso won, won a fi ko si ara igi kan, igi yen ni a n pe ni Ori, eyi ti
a fi so oruko ilu yii. Abe igi yen ni won maa n joko si gbategun. Leyin igba
die, won gba a lero lati lo pe awon ara won toku lati wa pago sibe, lati din
wahala lilo bibo ku. Sugbon ki won too lo, won bu iyepe ibe dani, won si lo
beere lowo awon onifa boya ibe dara lati gbe. Igba ti won gbe ifa sanle, ifa so
pe ibi ti won wa yen gan an, ilu won lo je, atipe igi ti won n fi aso ko si
iyen, igi Ori loruko e, nitori naa ki won maa bo igi na lodoodun, nitori pe,
iya olomo wewe ni igi yen.
AWIKONKO: Abule meloo lo wa labe Idi-Ori.
BAALE:
Abule marundinlogbon lo wa labe Idi-Ori. Onikaluku lo si ni Baale ti e.
AWIKONKO: Kini anfaani igi Ori yi, ti won fi n bo.
Bawo ni won se n bo?
BAALE:
E se. Iyan, Obe Egusi ati Eja gbigbe ni ifa ni ki won maa fi bo igi Ori yi
nigba naa lohun. Kii se nnkan eleje ni won fi n bo. Ti won ba ti fee bo,
onikaluku a gbe iyan lati ile won lo sidi igi naa, ti won a si beere nnkan ti
won ba fe lowo e. Nnkan ti a ba ni pe, bi eeyan ko ba ri omo bi, ti o ba de idi
igi yi, to ba bo o, to si beere omo lowo e, leyin odun kan, o gbodo gbe omo naa
pada lo fi dupe, iyen ni pe igi to n gbo adura ni. Ko si nnkan naa ti won n
beere lodo igi yii ti won ko ni ri gba. Tori e lo se je pe to ba ti n di igba
odun, a ma n paaro aso funfun ti a fi yi lara, iyen laa n so pe iya ti paaro
aso e. eekan lodun ni a maa n paaro aso e.
AWIKONKO: Kini Pataki ayeye odun Idi-Ori atipe ki
lawon idagbasoke ati anfaani to ti jade lati ara ayeye yii?
BAALE:
Mo ti so leekan pe, nnkan ti a ba lowo awon Baba nla wa ni, a o si gbodo je ko
parun. Lara awon anfaani e ni isokan gbogbo omo Idi-Ori ati idagbasoke ilu ni a
fi n se. Ko ri bayii tele ki n too di Baale, sugbon latigba ti mo ti de, mo ti
mu opolopo olaju wo, eyi to je kawon eeyan tewogba. Kii kuku se pe oogun ni a n
se. iyan, obe egusi ati eje gbigbe ni a fi n sodun naa.
AWIKONKO: A ri awon ilu to je pe won o dagba to ilu
Idi-Ori sugbon ti won ti ni idagbasoke to see toka si, ki lo de ti iru eyi ko
ri bee ni Idi-Ori?
BAALE:
Ibeere to dara ni. Mo dupe lowo yin. Iyen lo mu wa lati dide dide pe ka ja fun
eto wa nitori pe gbogbo awon ilu to je pe nigba ti won jo de ibi, awon bii
Ibogun, Akinale, Onigbedu, Sango, Ifo ni won wa ni Idi-Ori tele ko too di pe
onikaluku won kuro lati lo tedo sibo mi ran. Ki lo si faa? Idi e ni pe, nigba ti
won da oko titi, ti won ko fi bee ri ere to po. Ti won sakiyesi pe ile yen ko
dara fun koko lati bu yaari, eyi lo mu ki won kuro lati lo sibo miran. Nipa ti
idagbasoke, awon ilu ti mo n daruko yi, oju ona ni won wa, sugbon ti ijoba ba
fee so ona, ibe ni won n sise gba. Nnkan to fa ifaseyin ba Idi-Ori nipe ko bo
si oju ona, a maa ya wole ni. Sugbon ni bayii, a ti n rawo ebe sijoba ipinle
Ogun lati foju aanu wo wa lati ranwa lowo. Eleekeji ni pe, awon ajagungbale ko
je ka gbadun bo tile je pe wahala naa se se n dinku ni. Opo awon eeyan ni won
ti wa wipe awon fee wa da ile ise sile, sugbon ti won ba de, awon ajagungbale
lo maa da won lowo ko. Sugbon pelu ofin tijoba gbe kale, won ti dinku. Mo si
gbagbo pe laipe, itesiwaju yoo de.
AWIKONKO: Bawo ni yiyan Baale se bere atipe ki lo faa
ti ko tii si Oba nilu Idi-Ori?
BAALE:
Latigba ti won ti tedo sibi ni won ti n yan olori bo tile je pe ko si Baale,
nitori pe won fowosowopo. Eni ti o ba si dagba ju lo maa n se olori. Nigba ti
oju bere sii la lawon eeyan wa wo o pe o ye kawon yan Baale, to si je pe ijoba
naa ti da si. Itu merin lo wa nibi, ti itu kan ba papoda, itu miran a dide lati
je, kii se pe won gbogun tira won ki won too le de ipo naa. Awon ara itu kookan
ni won maa faayan kale. Ni ti oro oloba de, nnkan to je mi logun ni idagbasoke
kii se ipo tabi oye. Leyin ti mo de ni mo se ina ti mo si rii pe omi wa
kaakiri. A ti n gbe igbese lori oro osibitu ati ile eko. Ijoba la n ro lati
tete da wa lohun.
AWIKONKO: Nje e o lero pe bi e se fi aaye gba awon ajoji
lati maa ni Baale ti won ko le sakoba fun yin lojo iwaju.
BAALE:
Ko le ri be. Awon ajoji to wa nilu, won po, to si je pee de otooto ni onikaluku
n so. Ti a ba fee se ipade gbogboogbo, gbogbo wa o kan le kori jo, a nilo
asoju, eyi lo faa ti a fi woo pe kawon naa ni Baale ti won. Latigba ti a ti
bere, a o tii kabamo, a o si ni kabamo.
AWIKONKO: Ki le fee so nipa igbese ti ijoba ipinle
Ogun n gbe bayii lori bi won se so pe awon lawon yoo maa sakoso oro oloye ati
jije Oba bayii nipinle Ogun?
BAALE:
Boya e o gbo alaye ijoba daadaa, ko si bi won se fee se, ni gbogbo ileto
kaakiri, won ni Olori awon Oba. Oba lo si le fi Baale je, leyin toun bay an
Baale ti e ni ijoba sese le fowo si lati fun ni iwe eri. Ijoba ko le deedee
gbera lati so pea won n lo si ileto kan lati so pe awon feeyan Baale tabi Oba,
to ba ri bee, o ti di oro oselu niyen.
AWIKONKO: Kini oro amoran yin fawon araalu paapaa
awon omo Idi Ori?
BAALE: E
se pupo. Oro amoran mi ni pe Oro amoran mi ni pe bi nkan ti le wu ko le to
lasiko yii, ki a jo fori ti nitori pe leyin okunkun biribiri, imole a tan,
Oluwa a ran wa lowo. Fawon omo Idi-Ori, e je ka tubo gbaruku ti asa wa, ki o ma
baa parun.
No comments:
Post a Comment