Ileejo fee da ejo ti ajo EFCC fi kan OGD nu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 29, 2017

Ileejo fee da ejo ti ajo EFCC fi kan OGD nu

Bi ere bi awada, ile ejo giga kan to fidi kale si Isabo nilu Abeokuta tii se olu-ilu ipinle Ogun ti setan lati da ejo sise owo ilu moku-moku ti ajo EFCC fi kan gomina ana, Otunba Gbenga Daniel nu.

Otunba Gbenga Daniel
Igbese yi fee waye latari bi awon eleri ti ajo naa, iyen ajo EFCC pep e ko wa jeri soro naa se ko lati yoju si kootu fun igba keta iru e.

Onidajo ile ejo naa, iyen Adajo Olanrewaju Mabekoje lo fi ehunu e han nigba ti igbejo miran tun waye lojo Isegun Tusde ose to koja nigba to pea won eleri sita lati wa soro, sugbon ti ri enikan ko dide lati soro.

AWIKONKO gbo pe ibinu ni Adajo Mabekoje fi soro wipe igba keta re e ti ajo EFCC maa kuna lati fi eleri e han bo tile je pe won ti n mu awon eleri wa nigba ti won bere ejo naa lodun 2012.

Sugbon ni bayii, bo tile je pe Adajo naa ti sun ojo igbejo miran siwaju di ojo karun osu karun odun yii, bee lo tun fi oro ikilo tii nidi pe ti ajo EFCC ba ko lati pese awon eleri to daju lojo naa, oun ko nii ro leemeeji koun too da ejo naa nu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI