Komisana
feto ilera nipinle Ogun, Dokita Babatunde Ipaye ti so pe osibitu aladani mejo
nijoba ipinle Ogun ti ti pa latari aigba iwe ase tuntun eyi ti won yoo fi maa
sise won.
Babatunde Ipaye |
Ipaye soro yi lakoko to n sabewo sawon osibitu naa nijoba ibile Ado-Odo Ota nipinle
naa lose to koja, o so pe opo awon osibitu naa lawon ti so fun pe ki won lo gba
iwe ase tuntun, sugbon ti won ko lati tele ase ijoba. O so pe, osibitu mejo
tijoba ti pa yii lo je ko pe 168 ti won ti ti pa kaakiri ipinle naa.
O ni opo
awon osibitu lo je pe won ko kun oju osuwon lati so pe won sise to ri si oro
ilera, to si je pe ayederu iwe ase ni won n lo lati fi sise, eyi to si n fa ki
won maa da emi awon eeyan legbodo. O so pe ise ti won n se ko bofin mu, atipe
awon ti won ko kosemose ni won po lawon osibitu aladani yi.
No comments:
Post a Comment