Egbe alajeseku dara lopolopo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 27, 2017

Egbe alajeseku dara lopolopo

Won ti gba awon araalu lamoran lati darapo mo egbe alajeseku to ba wa lagbegbe won nitori pe ohun nikan lo le yo awon eeyan kuro ninu isoro oro aje to dorikodo lorile ede Naijiria.

Awon oloye tuntun
Oro amoran yi jade nibi ifilole egbe alajeseku tuntun, Ifeoluwadolapo CT&CS ti won sese da sile lagbegbe Ita-Oshin nilu Abeokuta. Nigba to n soro, Baba Egbe naa, Ogbeni Sakiru Solanke so pe anfaani nla lo wa ninu ki eeyan darapo egbe alajeseku, paapaa lasiko tie to oro aje Naijiria n se segesege.

Okunrin naa ni bi eeyan ba darapo mo egbe naa, ti o si fi owo ba egbe se, ko nii pe ti yoo fi moke ninu okoowo to ba dawo le. O ni egbe alajeseku ti yato si ti tele to je pe awon olori egbe maa n gbe owo salo, sugbon oro ko ri bee mo bayi nitori pe ijoba gan lo n sakose egbe alajeseku lasiko yi, bee naa ni won ti ni ileese leka ile ise ijoba.

Nibi eto naa ni won tun ti yan awon oga agba ti yoo maa tuko egbe tuntun naa, lara won ni Ogbeni E.O Akintepede to je alaga egbe, Ogbeni Aremu Musilimu toun je igbakeji; Arabinrin F. Oluwaseun toun je Akowe ati Arabinrin Adekitan Solape toun naa je Akapo.

Alaga egbe tuntun ti won yan naa, Ogbeni Akintepede nigba to n soro dupe lowo Olorun ati Aare ile iya egbe won, Ojise Olorun S. Lijadu fun ipa to n ko nipa egbe alajeseku nilu Abeokuta, paapaa nipinle Ogun. O wa ro awon omo egbe naa lati fowosowo pelu awon alase ti won yan naa lati mu egbe naa goke agba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI